MATIU 7

7
Ẹ̀kọ́ nípa Dídá Ẹlòmíràn Lẹ́jọ́
(Luk 6:37-38, 41-42)
1“Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́.#Mak 4:24 2Nítorí irú ẹjọ́ tí ẹ bá dá eniyan ni Ọlọrun yóo dá ẹ̀yin náà. Irú ìwọ̀n tí ẹ bá lò fún eniyan ni Ọlọrun yóo lò fún ẹ̀yin náà. 3Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi tí ó wà lójú ìwọ alára? 4Tabi báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Jẹ́ kí ń bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí ó jẹ́ pé ìtì igi wà ní ojú tìrẹ alára? 5Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi tí ó wà lójú rẹ kúrò; nígbà náà o óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ.
6“Ẹ má ṣe fi nǹkan mímọ́ fún ajá, ẹ má sì ṣe fi ìlẹ̀kẹ̀ iyebíye yín siwaju ẹlẹ́dẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọn yóo fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn yóo sì pada bù yín jẹ!
Ẹ̀kọ́ nípa Ìtẹramọ́ Adura
(Luk 11:9-13)
7“Ẹ bèèrè, a óo sì fi fun yín. Ẹ wá kiri, ẹ óo sì rí. Ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín. 8Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè ni ó ń rí gbà; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá nǹkan kiri ni ó ń rí i; ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kanlẹ̀kùn ni à ń ṣí i sílẹ̀ fún. 9Ta ni ninu yín, tí ọmọ rẹ̀ bá bèèrè àkàrà, tí ó jẹ́ fún un ní òkúta? 10Tabi tí ó bà bèèrè ẹja, tí ó jẹ́ fún un ní ejò? 11Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fi ohun tí ó dára fún ọmọ yín, mélòó-mélòó ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóo fi ohun rere fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀.
12“Nítorí náà, gbogbo bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà ṣe sí wọn. Kókó Òfin ati ọ̀rọ̀ àwọn wolii nìyí.#Tob 4:15; Luk 6:31
Ẹnu-ọ̀nà tí Ó Fún
(Luk 13:24)
13“Ẹ gba ẹnu ọ̀nà tí ó fún wọlé. Ọ̀nà ọ̀run àpáàdì gbòòrò, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fẹ̀. Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń gba ibẹ̀. 14Ṣugbọn ọ̀nà ìyè há, ẹnu ọ̀nà rẹ̀ sì fún. Díẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n rí i.#Sir 15:17
Èso Igi ni A Fi Ń Mọ Igi
(Luk 6:43-44)
15“Ẹ ṣọ́ra fún àwọn wolii èké tí wọn máa ń wá sọ́dọ̀ yín. Ní òde, wọ́n dàbí aguntan, ṣugbọn ninu, ìkookò tí ó ya ẹhànnà ni wọ́n. 16Nípa iṣẹ́ ọwọ́ wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n. Kò sí ẹni tí ó lè ká èso àjàrà lórí igi ẹ̀wọ̀n agogo tabi kí ó rí èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹ̀gún ọ̀gàn.#Sir 27:6 17Bẹ́ẹ̀ gan-an ni: gbogbo igi tí ó bá dára a máa so èso tí ó dára; igi tí kò bá dára a máa so èso burúkú. 18Igi tí ó bá dára kò lè so èso burúkú; bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lè so èso rere. 19Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.#Mat 3:10; Luk 3:9 20Nítorí náà nípa èso wọn ni ẹ óo fi mọ̀ wọ́n.#Mat 12:33
Ìjẹ́wọ́ Ẹnu Kò Tó
(Luk 13:25-27)
21“Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa’ ni yóo wọ ìjọba ọ̀run, bíkòṣe àwọn tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 22Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wí fún mi ní ọjọ́ ìdájọ́ pé, ‘Oluwa, Oluwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.’ 23Ṣugbọn n óo wí fún wọn pé, ‘Èmi kò mọ̀ yín rí. Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ibi wọnyi!’#O. Daf 6:8
Ìpìlẹ̀ Meji
(Luk 6:47-49)
24“Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta. 25Òjò rọ̀; àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà; ṣugbọn kò wó, nítorí ìpìlẹ̀ rẹ̀ wà lórí àpáta.
26“Ṣugbọn ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí kò bá fi ṣe ìwà hù, ó dàbí òmùgọ̀ eniyan kan tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. 27Òjò rọ̀, àgbàrá dé, ẹ̀fúùfù sì kọlu ilé náà. Ó bá wó! Wíwó rẹ̀ sì bani lẹ́rù lọpọlọpọ.”
Àṣẹ Jesu
28Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ẹnu ya àwọn eniyan sí ẹ̀kọ́ rẹ̀; 29nítorí ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn amòfin wọn.#Mak 1:22; Luk 4:32.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀