MATIU 9

9
Jesu Wo Arọ kan Sàn
(Mak 2:1-12; Luk 5:17-26)
1Jesu wọ inú ọkọ̀, ó rékọjá sí òdìkejì òkun, ó bá dé ìlú ara rẹ̀.#9:1 Èyí ni Kapanaumu. 2Àwọn kan bá gbé arọ kan wá, ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ṣe ara gírí, ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
3Àwọn amòfin kan ń rò ninu ara wọn pé, “Ọkunrin yìí ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun.”
4Ṣugbọn Jesu mọ èrò inú wọn; ó bá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro èrò burúkú ninu ọkàn yín? 5Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ ni,’ tabi láti sọ pé, ‘Dìde, kí o máa rìn?’ 6Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji eniyan ni.” Nígbà náà ni ó wá wí fún arọ náà pé “Dìde, gbé ibùsùn rẹ, máa lọ sí ilé rẹ.”
7Arọ náà bá dìde, ó lọ sí ilé rẹ̀. 8Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n fi ògo fún Ọlọrun tí ó fi irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún eniyan.
Jesu Pe Matiu
(Mak 2:13-17; Luk 5:27-32)
9Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó rí ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Matiu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Kíá, ó bá dìde, ó ń tẹ̀lé e.
10Matiu se àsè ní ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n wá, tí wọn ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun. 11Nígbà tí àwọn Farisi rí i, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Kí ní ṣe tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”#Luk 15:1-2.
12Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. 13Ẹ lọ kọ́ ìtumọ̀ gbolohun yìí: Ọlọrun sọ pé, ‘Àánú ṣíṣe ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ rírú.’ Nítorí náà kì í ṣe àwọn olódodo ni mo wá pè, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”#a Mat 12:7; b Hos 6:6
Ìbéèrè nípa Ààwẹ̀
(Mak 2:18-22; Luk 5:33-39)
14Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí àwa ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kì í gbààwẹ̀?”
15Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa ṣọ̀fọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà lọ́dọ̀ wọn. Àkókò ń bọ̀ nígbà tí a óo gba ọkọ iyawo lọ́wọ́ wọn; wọn yóo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.
16“Kò sí ẹni tíí fi ìrépé aṣọ titun tí kò ì tíì wọ omi rí lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù, Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìrépé aṣọ titun náà yóo súnkì lára ògbólógbòó ẹ̀wù náà, yíya rẹ̀ yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. 17Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ògbólógbòó àpò awọ náà yóo bẹ́; ati ọtí ati àpò yóo sì ṣòfò. Ṣugbọn ninu àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí, ati ọtí ati àpò yóo wà ní ìpamọ́.”
Ọmọdebinrin Ìjòyè kan ati Obinrin Onísun Ẹ̀jẹ̀
(Mak 5:21-43; Luk 8:40-56)
18Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”
19Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
20Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu; 21nítorí ó ń sọ ninu ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá ti lè fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, ara mi yóo dá.”
22Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ.
23Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké. 24Ó ní, “Ẹ sún sẹ́yìn, nítorí ọmọde náà kò kú, ó ń sùn ni.” Wọ́n bá ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. 25Lẹ́yìn tí ó ti lé àwọn eniyan jáde, ó wọ inú ilé, ó mú ọmọbinrin náà lọ́wọ́, ọmọbinrin náà bá dìde. 26Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo agbègbè náà.
Jesu La Àwọn Afọ́jú Meji Lójú
27Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”
28Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”
29Ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú, ó ní, “Kí ó rí fun yín gẹ́gẹ́ bí igbagbọ yín.” 30Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.”
31Ṣugbọn nígbà tí wọ́n jáde, ńṣe ni wọ́n ń pòkìkí rẹ̀ káàkiri gbogbo agbègbè náà.
Jesu Wo Odi kan Sàn
32Bí àwọn afọ́jú náà ti jáde, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan mú ọkunrin kan, tí ẹ̀mí èṣù mú kí ó yadi, wá sọ́dọ̀ Jesu. 33Ṣugbọn bí ó ti lé ẹ̀mí èṣù náà jáde ni odi náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń sọ pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”
34Ṣugbọn àwọn Farisi ń sọ pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”#Mat 10:25; 12:24; Mak 3:22; Luk 11:15
Jesu Aláàánú
35Jesu ń rìn kiri ní gbogbo àwọn ìlú ati àwọn ìletò, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó sì ń wo oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera sàn.#Mat 4:23; Mak 1:39; Luk 4:44 36Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ eniyan náà, àánú wọn ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́, tí ọkàn wọn dààmú, tí ó sì rẹ̀wẹ̀sì.#Nọm 27:17; 1 A. Ọba 22:17; 2Kron 18:16; Isi 34:5; Mak 6:34 37Ó bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àwọn ohun tí ó tó kórè pọ̀, ninu oko, ṣugbọn àwọn òṣìṣẹ́ kò pọ̀. 38Nítorí náà ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ sí ibi ìkórè rẹ̀.”#Luk 10:2

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MATIU 9: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀