MAKU 7

7
Àṣà Ìbílẹ̀
(Mat 15:1-9)
1Àwọn Farisi ati àwọn amòfin kan tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu péjọ sí ọ̀dọ̀ Jesu. 2Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.
3(Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn. 4Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)#7:4 Àwọn Bibeli àtijọ́ mìíràn fi kún gbolohun yìí: ati àwọn ìrọ̀gbọ̀kú wọn.
5Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”
6Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé,
‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí,
ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi,
7asán ni sísìn tí wọn ń sìn mí,
ìlànà eniyan ni wọ́n fi ń kọ́ni
bí òfin Ọlọrun.’#Ais 27:13
8“Ẹ fi àṣẹ Ọlọrun sílẹ̀, ẹ wá dìmọ́ àṣà eniyan.”
9Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ. 10Nítorí Mose wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ’ ati pé, ‘Kí á pa ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àbùkù sí baba tabi ìyá rẹ̀.’#a Eks 20:12; Diut 5:16 b Eks 21:17; Lef 20:9 11Ṣugbọn ẹ̀yin wí pé, ‘Bí eniyan bá wí fún baba tabi ìyá rẹ̀ pé ohunkohun tí n bá fun yín, Kobani ni,’ (èyí ni pé ẹ̀bùn fún Ọlọrun ni), 12ẹ ti gbà pé ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní ohunkohun í ṣe fún baba tabi ìyá rẹ̀ mọ́. 13Ẹ fi àṣà ìbílẹ̀ yín yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ọpọlọpọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ẹ tún ń ṣe.”
Nǹkan Tí Ń Sọ Eniyan Di Àìmọ́
(Mat 15:10-20)
14Ó tún pe àwọn eniyan, ó ń wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ fi etí sílẹ̀, kí ọ̀rọ̀ mi ye yín. 15Kò sí ohun kan láti òde wá tí ó wọ inú eniyan lọ tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́. Ṣugbọn àwọn ohun tí ó ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. [ 16Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”]
17Nígbà tí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, tí ó wọ inú ilé lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí. 18Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin náà kò ní òye? Kò ye yín pé kì í ṣe nǹkan tí ó bá wọ inú eniyan lọ níí sọ eniyan di aláìmọ́? 19Nítorí kì í wọ inú ọkàn lọ, bíkòṣe inú ikùn, a sì tún jáde.” (Báyìí ni ó pe gbogbo oúnjẹ ní mímọ́.)
20Ó tún fi kún un pé, “Àwọn nǹkan tí ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. 21Nítorí láti inú ọkàn eniyan ni ète burúkú ti ń jáde: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn, 22àgbèrè, ojúkòkòrò, ìwà ìkà, ẹ̀tàn, ìwà wọ̀bìà, owú jíjẹ, ọ̀rọ̀ ìṣáátá, ìwà ìgbéraga, ìwà òmùgọ̀. 23Láti inú ni gbogbo àwọn nǹkan ibi wọnyi ti ń wá, àwọn ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.”
Igbagbọ Obinrin Ará Fonike ti Siria
(Mat 15:21-28)
24Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́. 25Obinrin kan tí ọdọmọbinrin rẹ̀ ní ẹ̀mí èṣù gbọ́ nípa rẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó wá kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. 26Ọmọ ìbílẹ̀ Giriki ni obinrin yìí, a bí i ní Fonike ní Siria. Ó ń bẹ̀ ẹ́ kí ó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọdọmọbinrin òun. 27Jesu wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ rí oúnjẹ jẹ yó ná, nítorí kò dára kí á mú oúnjẹ ọmọ kí á sọ ọ́ fún ajá.”
28Ṣugbọn obinrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà, ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀rúnrún oúnjẹ àwọn ọmọ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili.”
29Jesu dá a lóhùn pé, “Nítorí gbolohun rẹ yìí, máa lọ sí ilé rẹ, ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò ninu ọmọ rẹ.”
30Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀, ó rí ọmọde náà tí ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, tí ẹ̀mí burúkú náà ti jáde kúrò lára rẹ̀.
Jesu Wo Adití Akólòlò kan Sàn
31Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá.#7:31 Ní Giriki: Dekapolisi. 32Wọ́n wá gbé adití kan tí ń kólòlò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ lé e. 33Ó bá mú un bọ́ sí apá kan, kúrò láàrin àwọn ọ̀pọ̀ eniyan, ó ti ìka rẹ̀ bọ ọkunrin náà létí, ó tutọ́, ó fi kan ahọ́n rẹ̀. 34Ó gbé ojú sí òkè ọ̀run, ó kẹ́dùn, ó bá ní, “Efata,” ìtumọ̀ èyí tí i ṣe, “Ìwọ, ṣí.”
35Etí ọkunrin náà bá ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀ gaara. 36Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó. 37Ẹnu ya gbogbo wọn kọjá ààlà, wọ́n ń wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára: ó mú kí adití gbọ́ràn, ó mú kí odi sọ̀rọ̀.”
Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan
(Mat 15:32-39)

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

MAKU 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀