NEHEMAYA 1
1
1Ìtàn Nehemaya ọmọ Hakalaya.
Ẹ̀dùn Ọkàn Nehemaya fún Jerusalẹmu
Ní oṣù Kisilefi, ní ogún ọdún tí Atasasesi jọba ní ilẹ̀ Pasia, mo wà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ náà, 2Hanani, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi, pẹlu àwọn kan tọ̀ mí wá láti ilẹ̀ Juda, mo bá bèèrè àwọn Juu tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lọ sóko ẹrú, mo sì tún bèèrè nípa Jerusalẹmu. 3Wọ́n sọ fún mi pé, “Inú wahala ńlá ati ìtìjú ni àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lẹ́rú wà, ati pé odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀, iná sì ti jó gbogbo ẹnu ọ̀nà rẹ̀.”
4Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo jókòó, mo sọkún, mo sì kẹ́dùn fún ọpọlọpọ ọjọ́.
Mo bá bẹ̀rẹ̀ sí gbààwẹ̀, mo sì ń gbadura sí Ọlọrun ọ̀run pé, 5“OLUWA Ọlọrun ọ̀run, Ọlọrun tí ó tóbi tí ó sì lẹ́rù, Ọlọrun tíí máa pa majẹmu ati ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ mọ́ pẹlu àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, 6tẹ́tí sílẹ̀, bojú wò mí, kí o sì fetí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mò ń gbà tọ̀sán-tòru nítorí àwọn ọmọ Israẹli, iranṣẹ rẹ, tí mo sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ṣẹ̀ ọ́. Wò ó, èmi ati ìdílé baba mi ti dẹ́ṣẹ̀. 7A ti hùwà burúkú sí ọ, a kò sì pa àwọn òfin, ati ìlànà ati àṣẹ rẹ tí o pa fún Mose iranṣẹ rẹ mọ́. 8Ranti ìlérí tí o ṣe fún Mose, iranṣẹ rẹ, pé, ‘Bí ẹ kò bá jẹ́ olóòótọ́, n óo fọn yín káàkiri sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, 9ṣugbọn tí ẹ bá pada sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa òfin mi mọ́, tí ẹ sì ń tẹ̀lé e, bí ẹ tilẹ̀ fọ́nká lọ sí ọ̀nà jíjìn réré, n óo ṣà yín jọ, n óo sì ko yín pada sí ibi tí mo ti yàn pé ẹ óo ti máa sìn mí kí orúkọ mi lè máa wà níbẹ̀.’ #Lef 26:33 #Diut 30:1-5
10“Iranṣẹ rẹ ni wọ́n, eniyan rẹ sì ni wọ́n, àwọn tí o ti fi ipá ati agbára ọwọ́ rẹ rà pada. 11OLUWA, tẹ́tí sí adura èmi iranṣẹ rẹ, tí mo bẹ̀rù orúkọ rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, kí n sì rí ojurere ọba.”
Èmi ni agbọ́tí ọba ní àkókò náà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NEHEMAYA 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010