NỌMBA 14
14
Àwọn Eniyan náà Kùn
1Gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí ké, wọn sì fi gbogbo òru ọjọ́ náà sọkún. 2Gbogbo wọn ń kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ó sàn fún wa kí á kúkú kú sí Ijipti tabi ní aṣálẹ̀ yìí. 3Kí ló dé tí OLUWA fi ń mú wa lọ sí ilẹ̀ náà kí àwọn ọ̀tá wa lè pa wá, kí wọ́n sì kó àwọn aya ati àwọn ọmọ wa lẹ́rú. Ǹjẹ́ kò ní sàn fún wa kí á pada sí Ijipti?” 4Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á yan olórí, kí á pada sí Ijipti.”
5Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀ níwájú àwọn eniyan náà. 6Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune tí wọ́n wà lára àwọn amí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn. 7Wọ́n sọ fún ìjọ eniyan Israẹli pé, “Ilẹ̀ tí a lọ wò náà jẹ́ ilẹ̀ tí ó dára lọpọlọpọ. 8Bí inú OLUWA bá dùn sí wa, yóo mú wa dé ilẹ̀ náà, yóo sì fún wa; àní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó lẹ́tù lójú. 9Ẹ má lòdì sí OLUWA, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà. A óo ṣẹgun wọn, nítorí kò sí ààbò fún wọn mọ́. OLUWA wà pẹlu wa, ẹ má bẹ̀rù.”#Heb 3:16. 10Bí àwọn eniyan náà ti ń gbèrò láti sọ wọ́n lókùúta pa ni wọ́n rí i tí ògo OLUWA fara hàn ní Àgọ́ Àjọ.
Mose Gbadura fún Àwọn Eniyan náà
11OLUWA sọ fún Mose pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo ti kọ̀ mí sílẹ̀ pẹ́ tó. Yóo ti pẹ́ tó kí wọ́n tó máa gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrin wọn? 12N óo rán àjàkálẹ̀ àrùn láti pa gbogbo wọn run, n óo sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, ṣugbọn n óo sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè tí yóo pọ̀ ju àwọn wọnyi lọ, tí yóo sì lágbára jù wọ́n lọ.”
13Mose bá sọ fún OLUWA pé, “Ní ààrin àwọn ará Ijipti ni o ti mú àwọn eniyan wọnyi jáde pẹlu agbára. Nígbà tí wọn bá sì gbọ́ ohun tí o ṣe sí wọn, wọn yóo sọ fún àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ yìí. 14Àwọn eniyan wọnyi sì ti gbọ́ pé ìwọ OLUWA wà pẹlu wa ati pé à máa rí ọ ninu ìkùukùu nígbà tí o bá dúró lókè ibi tí a wà; nígbà tí o bá ń lọ níwájú wa ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu lọ́sàn-án, ati ninu ọ̀wọ̀n iná lóru. 15Nisinsinyii, bí o bá pa àwọn eniyan yìí bí ẹni tí ó pa ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gbọ́ òkìkí rẹ yóo wí pé; 16o pa àwọn eniyan rẹ ninu aṣálẹ̀ nítorí pé o kò lè kó wọn dé ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí fún wọn. 17Nítorí náà OLUWA, èmi bẹ̀ Ọ́, fi agbára ńlá rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ pé, 18‘OLUWA kì í tètè bínú, àánú rẹ̀ sì pọ̀. A máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìṣedéédé ji eniyan, ṣugbọn kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà. A máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta ati ikẹrin.’#Eks 20:5-6; 34:6-7; Diut 5:9-10; 7:9-10 19Nisinsinyii OLUWA, mo bẹ̀ Ọ́, ro títóbi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan yìí jì wọ́n bí o ti ń dáríjì wọ́n láti ìgbà tí wọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.”#Eks 32
20OLUWA dáhùn pé, “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bẹ̀ rẹ. 21Ṣugbọn nítòótọ́, níwọ̀n ìgbà tí mo wà láàyè, tí ògo mi sì kún ayé, 22àwọn eniyan wọnyi, tí wọ́n ti rí ògo mi ati àwọn iṣẹ́ ìyanu tí mo ṣe ní Ijipti ati ninu aṣálẹ̀, ṣugbọn tí wọ́n ti dán mi wò nígbà mẹ́wàá, tí wọ́n sì ṣàìgbọràn sí mi, 23ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn. Ẹyọ kan ninu àwọn tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀ wọnyi kò ní débẹ̀.#Heb 3:18 24Ṣugbọn nítorí pé iranṣẹ mi, Kalebu, ní ẹ̀mí tí ó yàtọ̀, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí mi, n óo mú un dé ilẹ̀ tí ó lọ wò, ilẹ̀ náà yóo sì jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀.#Joṣ 14:9-12 25Nítorí pé àwọn Amaleki ati ará Kenaani ń gbé àfonífojì, ní ọ̀la, ẹ gbéra, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sinu aṣálẹ̀.”
OLUWA Jẹ Àwọn Eniyan náà Níyà Nítorí pé wọ́n Kùn
26OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, 27“Yóo ti pẹ́ tó tí àwọn eniyan burúkú wọnyi yóo fi máa kùn sí mi? Mo ti gbọ́ gbogbo kíkùn tí wọn ń kùn sí mi. 28Nisinsinyii, sọ fún wọn pé, ‘Bí mo tì wà láàyè, n óo ṣe yín gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. 29Ẹ óo kú ninu aṣálẹ̀ yìí; gbogbo yín; ohun tí ó ṣẹ̀ láti ẹni ogún ọdún lọ sókè, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kùn sí mi.#Heb 3:17 30Ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní wọ ilẹ̀ tí mo ti búra pé yóo jẹ́ ibùgbé yín, àfi Kalebu ọmọ Jefune ati Joṣua, ọmọ Nuni. 31Ṣugbọn àwọn ọmọ yín tí ẹ sọ pé ogun yóo kó, ni n óo mú dé ilẹ̀ náà; ilẹ̀ tí ẹ kọ̀ sílẹ̀ yóo sì jẹ́ tiwọn. 32Ṣugbọn ní tiyín, ẹ ó kú ninu aṣálẹ̀ níhìn-ín. 33Àwọn ọmọ yín yóo rìn káàkiri ninu aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, gẹ́gẹ́ bí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún aiṣododo yín, títí gbogbo yín yóo fi kú tán.#A. Apo 7:36. 34Ẹ óo sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ogoji ọdún. Ọdún kọ̀ọ̀kan yóo dípò ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ninu ogoji ọjọ́ tí àwọn amí fi wo ilẹ̀ náà. Ẹ óo rí ibinu mi. 35Mo ti ṣe ìlérí pé n óo ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ẹ̀yin eniyan burúkú, tí ẹ̀ ń lòdì sí mi wọnyi. Gbogbo yín ni yóo kú ninu aṣálẹ̀ yìí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”
36OLUWA bá mú àwọn tí Mose rán lọ wo ilẹ̀ náà tí wọ́n sì mú ìròyìn burúkú wá, àwọn tí wọ́n mú kí àwọn eniyan náà kùn sí Mose, 37ó bá fi àrùn burúkú pa wọ́n. 38Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefune nìkan ni wọ́n yè ninu àwọn amí mejila náà.
Ìgbà Kinni Tí Wọ́n Gbìyànjú àtigba Ilẹ̀ náà
(Diut 1:41-46)
39Nígbà tí Mose sọ ohun tí OLUWA sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n káàánú gidigidi. 40Wọ́n bá gbéra ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, wọ́n lọ sí agbègbè olókè, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́ a ti dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn nisinsinyii a ti ṣetán láti lọ gba ilẹ̀ náà tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.”
41Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe àìgbọràn sí àṣẹ OLUWA nisinsinyii? Ohun tí ẹ fẹ́ ṣe yìí kò ní yọrí sí rere. 42Ẹ má lọ nítorí OLUWA kò ní wà pẹlu yín, àwọn ọ̀tá yín yóo sì ṣẹgun yín. 43Ẹ óo kú nígbà tí ẹ bá ń bá àwọn ará Amaleki ati Kenaani jagun. OLUWA kò ní wà pẹlu yín nítorí pé ẹ ti ṣe àìgbọràn sí i.”
44Sibẹsibẹ àwọn eniyan náà lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Àpótí Majẹmu OLUWA tabi Mose kò kúrò ní ibùdó. 45Àwọn ará Amaleki ati Kenaani tí ń gbé ibẹ̀ bá wọn jagun, wọ́n ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì lé wọn títí dé Horima.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 14: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010