NỌMBA 16
16
Ọ̀tẹ̀ tí Kora, Datani ati Abiramu Dì
1Kora ọmọ Iṣari láti inú ìdílé Kohati ọmọ Lefi, pẹlu Datani ati Abiramu àwọn ọmọ Eliabu, pẹlu Ooni ọmọ Peleti láti inú ẹ̀yà Reubẹni gbìmọ̀ pọ̀,#Jud 11 2wọ́n kó aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọ́n jọ jẹ́ olórí ati olókìkí ninu àwọn ọmọ Israẹli sòdí láti dìtẹ̀ mọ́ Mose. 3Wọ́n dojú kọ Mose ati Aaroni, wọ́n ní, “Ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, nítorí pé olukuluku àwọn ọmọ Israẹli ni ó jẹ́ ẹni ìyàsọ́tọ̀ fún OLUWA, OLUWA sì ń bẹ láàrin wọn. Kí ló dé tí ẹ̀yin gbé ara yín ga ju gbogbo àwọn eniyan OLUWA lọ?”
4Nígbà tí Mose gbọ́, ó dojúbolẹ̀, 5Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun. 6Ní ọ̀la ìwọ ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ, ẹ mú àwo turari, 7kí ẹ fi iná sinu wọn, kí ẹ sì gbé wọn lọ siwaju OLUWA. Ẹni tí OLUWA bá yàn ni yóo jẹ́ ẹni mímọ́; ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí kọjá ààyè yín, ẹ̀yin ọmọ Lefi!”
8Mose bá kọjú sí Kora, ó ní: “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọmọ Lefi! 9Ṣé nǹkan kékeré ni, pé Ọlọrun Israẹli yà yín sọ́tọ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu Àgọ́ Àjọ OLUWA, ati fún ìjọ eniyan Israẹli? 10OLUWA ti fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ Lefi yòókù ní anfaani yìí, ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń ṣe ojú kòkòrò sí iṣẹ́ alufaa. 11Ṣé ẹ kò mọ̀ pé OLUWA ni ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí, nígbà tí ẹ̀ ń fi ẹ̀sùn kan Aaroni? Ta ni Aaroni tí ẹ̀yin ń fi ẹ̀sùn kàn?”
12Mose bá ranṣẹ lọ pe Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ṣugbọn wọ́n kọ̀ wọn kò wá. 13Wọ́n ní, “O mú wa wá láti ilẹ̀ ọlọ́ràá Ijipti tí ó kún fún wàrà ati fún oyin, o fẹ́ wá pa wá sinu aṣálẹ̀ yìí, sibẹ kò tó ọ, o tún fẹ́ sọ ara rẹ di ọba lórí gbogbo wa. 14O kò tíì kó wa dé ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó kún fún wàrà ati oyin, tabi kí o fún wa ní ọgbà àjàrà ati oko. Ṣé o fẹ́ fi júújúú bo àwọn eniyan wọnyi lójú ni, a kò ní dá ọ lóhùn.”
15Mose bínú gidigidi, ó sì sọ fún OLUWA pé, “OLUWA, má ṣe gba ẹbọ àwọn eniyan wọnyi. N kò ṣe ibi sí ẹnikẹ́ni ninu wọn bẹ́ẹ̀ ni ń kò gba kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnikẹ́ni wọn.”
16Mose bá sọ fún Kora pé, “Ní ọ̀la kí ìwọ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ wá siwaju Àgọ́ Àjọ. Aaroni pẹlu yóo wà níbẹ̀. 17Kí olukuluku yín ati Aaroni pẹlu mú àwo turari rẹ̀, kí ẹ sì fi turari sí i láti rúbọ sí OLUWA. Gbogbo rẹ̀ yóo jẹ́ aadọtaleerugba (250) àwo turari.” 18Olukuluku wọn sì mú àwo turari tirẹ̀, wọ́n fi ẹ̀yinná ati turari sí i, wọ́n sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ pẹlu Mose ati Aaroni. 19Kora kó gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni; Ògo OLUWA sì farahàn, àwọn eniyan náà sì rí i. 20OLUWA sì sọ fún Mose ati Aaroni pé: 21“Ẹ bọ́ sí apá kan kí n lè rí ààyè pa àwọn eniyan náà run ní ìṣẹ́jú kan.”
22Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?”
23OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, 24“Sọ fún àwọn eniyan náà kí wọ́n kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu.”
25Mose bá dìde pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Datani ati Abiramu. 26Ó sì sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn ọkunrin burúkú wọnyi, kí ẹ má sì fọwọ́ kan nǹkankan tí ó jẹ́ tiwọn, kí ẹ má baà pín ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.” 27Àwọn eniyan náà bá kúrò ní agbègbè àgọ́ àwọn Kora ati Datani ati Abiramu.
Datani ati Abiramu pẹlu aya ati àwọn ọmọ wọn jáde wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ wọn. 28Mose sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Nisinsinyii ni ẹ óo mọ̀ pé èmi kọ́ ni mo yan ara mi ṣugbọn OLUWA ni ó rán mi láti ṣe gbogbo ohun tí mò ń ṣe. 29Bí àwọn ọkunrin wọnyi bá kú ikú tí kò mú ìbẹ̀rù lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, a jẹ́ wí pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán mi. 30Ṣugbọn bí OLUWA bá ṣe ohun tí etí kò gbọ́ rí, tí ilẹ̀ bá yanu tí ó gbé wọn mì pẹlu àwọn eniyan wọn ati àwọn ohun ìní wọn, tí wọn sì bọ́ sinu ibojì láàyè, ẹ óo mọ̀ pé wọ́n ti kọ OLUWA sílẹ̀.”
31Ní kété tí Mose parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ilẹ̀ tí wọ́n dúró lé lórí là sí meji, 32ó yanu, ó sì gbé wọn mì, ati àwọn ati ìdílé wọn, ati ohun ìní wọn. Ilẹ̀ sì gbé Kora mì pẹlu àwọn eniyan rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní wọn. 33Gbogbo wọn, ati ohun ìní wọn, ati àwọn eniyan wọn, lọ sí ipò òkú láàyè, ilẹ̀ panudé, wọ́n sì ṣègbé kúrò láàrin ìjọ eniyan Israẹli. 34Àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ sì sálọ nígbà tí wọn gbọ́ igbe wọn. Wọ́n bẹ̀rù kí ilẹ̀ má baà gbé àwọn náà mì.
35OLUWA sì rán iná láti run àwọn aadọtaleerugba (250) ọkunrin tí wọn mú àwo turari wá siwaju Àgọ́ Àjọ.#Sir 45:18-20
Àwọn Àwo Turari
36OLUWA sọ fún Mose pé, 37“Sọ fún Eleasari ọmọ Aaroni, alufaa pé kí ó kó àwọn àwo turari wọ̀n-ọn-nì kúrò láàrin àjókù àwọn eniyan náà. Kí ó sì da iná inú wọn káàkiri jìnnà jìnnà nítorí àwọn àwo turari náà jẹ́ mímọ́. 38Kí ó mú àwo turari àwọn ọkunrin tí wọ́n kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kí ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ, nítorí níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti mú wọn wá siwaju OLUWA, wọ́n ti di mímọ́. Èyí yóo sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli.” 39Eleasari bá kó àwọn àwo turari náà tí àwọn tí ó jóná fi rú ẹbọ, ó fi wọ́n rọ àwo fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ fún ìbòrí pẹpẹ. 40Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.
Aaroni Gba Àwọn Eniyan náà Là
41Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.” 42Ó sì ṣe nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni, wọn bojúwo ìhà Àgọ́ Àjọ, wọ́n sì rí i tí ìkùukùu bò ó, ògo OLUWA sì farahàn. 43Mose ati Aaroni lọ dúró níwájú Àgọ́ Àjọ, 44OLUWA sì sọ fún Mose pé, 45“Kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi kí n lè pa wọ́n run ní ìṣẹ́jú kan.”
Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀. 46Mose sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo turari rẹ, fi ẹ̀yinná sinu rẹ̀ láti orí pẹpẹ kí o sì fi turari sí i. Ṣe kíá, lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan náà láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí ibinu OLUWA ti ru, àjàkálẹ̀ àrùn sì ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.” 47Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Mose. Ó mú àwo turari rẹ̀, ó sáré lọ sí ààrin àwọn eniyan náà. Nígbà tí ó rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ́ sílẹ̀, ó fi turari sí i, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. 48Aaroni dúró ní ààrin àwọn òkú ati alààyè, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró.#Ọgb 18:20-25. 49Àwọn tí ó kú jẹ́ ẹgbaa meje ó lé ẹẹdẹgbẹrin (14,700) láìka àwọn tí ó kú pẹlu Kora. 50Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn náà dáwọ́ dúró, Aaroni pada sọ́dọ̀ Mose lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 16: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010