NỌMBA 20
20
Ohun Tí Ó Ṣẹlẹ̀ ní Kadeṣi
(Eks 17:1-7)
1Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.
2Kò sí omi fún àwọn eniyan náà níbi tí wọ́n ṣe ibùdó sí, wọ́n sì kó ara wọn jọ sí Mose ati Aaroni. 3Wọ́n ń kùn pé: “Ìbá sàn fún wa bí ó bá jẹ́ pé a ti kú nígbà tí àwọn arakunrin wa kú níwájú OLUWA. 4Kí ló dé tí ẹ fi mú àwọn eniyan OLUWA wá sinu aṣálẹ̀ yìí? Ṣé kí àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú ni? 5Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.” 6Mose ati Aaroni kúrò níwájú àwọn eniyan náà, wọ́n lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, wọ́n dojúbolẹ̀, ògo OLUWA sì farahàn.
7OLUWA sọ fún Mose pé, 8“Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.” 9Mose lọ mú ọ̀pá náà níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.
10Òun ati Aaroni kó gbogbo àwọn eniyan náà jọ siwaju àpáta náà. Mose sì wí fún wọn pé, “ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀, ṣé kí á mú omi jáde fun yín láti inú àpáta yìí?” 11Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu.#Ọgb 11:4
12Ṣugbọn OLUWA bínú sí Mose ati Aaroni, ó ní, “Nítorí pé ẹ kò gbà mí gbọ́, ẹ kò sì fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà, ẹ̀yin kọ́ ni yóo kó wọn dé ilẹ̀ tí mo ti ṣèlérí láti fún wọn.”
13Èyí ni omi Meriba, nítorí níbẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbolohun asọ̀ pẹlu OLUWA, tí OLUWA sì fi ara rẹ̀ hàn wọ́n pé mímọ́ ni òun.#Eks 17:1-7.
Ọba Edomu kò Jẹ́ kí Àwọn Ọmọ Israẹli Kọjá
14Mose rán oníṣẹ́ láti Kadeṣi sí ọba Edomu pé, “Arakunrin rẹ ni àwa ọmọ Israẹli jẹ́, o sì mọ gbogbo àwọn ìṣòro tí ó ti dé bá wa. 15Bí àwọn baba ńlá wa ṣe lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ará Ijipti lo àwọn baba ńlá wa ati àwa náà ní ìlò ẹrú. 16Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ. 17Jọ̀wọ́ gbà wá láàyè kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà sinu oko yín tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi inú kànga yín. Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, a kò ní yà sí ọ̀tún tabi òsì títí tí a óo fi kọjá ilẹ̀ rẹ.”
18Ṣugbọn àwọn ará Edomu dáhùn pé, “A kò ní jẹ́ kí ẹ gba ilẹ̀ wa kọjá, bí ẹ bá sì fẹ́ kọjá pẹlu agídí, a óo ba yín jagun.”
19Àwọn ọmọ Israẹli ní, “Ojú ọ̀nà ni a óo máa tọ̀, bí àwa tabi ẹran wa bá tilẹ̀ mu omi yín, a óo sanwó rẹ̀. Ohun kan tí a sá fẹ́ ni pé kí ẹ jẹ́ kí á kọjá.”
20Àwọn ará Edomu tún dáhùn pé, “Rárá o, ẹ kò lè kọjá.” Wọ́n sì jáde pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun ati agbára ogun láti lọ dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Israẹli. 21Nígbà tí àwọn ará Edomu kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli gba ilẹ̀ wọn kọjá, wọ́n bá gba ọ̀nà ibòmíràn.
Ikú Aaroni
22Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Kadeṣi, wọ́n wá sí òkè Hori 23ní agbègbè ilẹ̀ Edomu. Níbẹ̀ ni OLUWA ti sọ fún Mose ati Aaroni pé, 24“Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba. 25Nítorí náà mú Aaroni ati ọmọ rẹ̀ Eleasari wá sórí òkè Hori. 26Níbẹ̀ ni kí o ti bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, kí o gbé e wọ Eleasari. Níbẹ̀ ni Aaroni óo kú sí.” 27Mose ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, gbogbo wọn sì gòkè Hori lọ níwájú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli. 28Mose bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, ó gbé e wọ Eleasari. Aaroni sì kú sí orí òkè náà, Mose ati Eleasari sì sọ̀kalẹ̀.#Eks 29:29; Nọm 33:38; Diut 10:6. 29Nígbà tí àwọn eniyan náà mọ̀ pé Aaroni ti kú, wọ́n ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún ọgbọ̀n ọjọ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
NỌMBA 20: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010