ÌWÉ ÒWE 11

11
1OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké,
òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí.
2Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e,
ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀.
3Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn,
ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n.
4Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu,
ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú,
5Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́,
ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀.
6Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n,
ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn.
7Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú,
ìrètí wọn yóo di asán,
bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo.
8OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu,
ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.
9Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máa
fi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́,
ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀.
10Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo,
gbogbo ará ìlú a máa yọ̀,
nígbà tí eniyan burúkú bá kú,
gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀.
11Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga,
ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú.
12Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n,
ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́.
13Olófòófó a máa tú àṣírí,
ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́.
14Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú,#Ọgb 6:24
ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu.
15Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu,
ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.
16Obinrin onínúrere gbayì,
ṣugbọn ọrọ̀ nìkan ni ìkà yóo ní.
17Ẹni tí ó ṣoore ṣe é fún ara rẹ̀,
ẹni tí ó sì ń ṣìkà ó ń ṣe é fún ara rẹ̀.
18Owó ọ̀yà èké ni eniyan burúkú óo gbà,
ṣugbọn ẹni tí ó bá hùwà òdodo yóo gba èrè òtítọ́.
19Ẹni tí ó dúró ṣinṣin lórí òdodo yóo yè,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń lépa ibi yóo kú.
20Ẹni ìríra ni àwọn alágàbàgebè lójú OLUWA,
ṣugbọn àwọn tí ọ̀nà wọn mọ́ ni ìdùnnú fún un.
21Dájúdájú ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà,
ṣugbọn a óo gba àwọn olódodo là.
22Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀
ni obinrin tí ó lẹ́wà tí kò ní làákàyè.
23Ìfẹ́ ọkàn olódodo a máa yọrí sí rere,
ṣugbọn ìrètí eniyan burúkú a máa já sí ibinu.
24Ẹnìkan wà tíí máa ṣe ìtọrẹ àánú káàkiri,
sibẹsibẹ àníkún ni ó ń ní,
ẹnìkan sì wà tí ó háwọ́,
sibẹsibẹ aláìní ni.
25Ẹni tí ó bá lawọ́ yóo máa ní àníkún,
ẹni tí ó bá jẹ́ kí ọkàn ẹlòmíràn balẹ̀,
ọkàn tirẹ̀ náà yóo balẹ̀.
26Ẹni tí ó bá ń kó oúnjẹ pamọ́, yóo gba ègún sórí,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ta oúnjẹ, yóo rí ibukun gbà.
27Ẹni tí ó bá ń wá ire, yóo rí ojurere,
ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ibi, ibi yóo bá a.
28Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóo rẹ̀ dànù bí òdòdó,
ṣugbọn olódodo yóo rú bí ewé tútù.
29Ẹni tí ó bá mú ìyọnu dé bá ìdílé rẹ̀ yóo jogún òfo,
òmùgọ̀ ni yóo sì máa ṣe iranṣẹ ọlọ́gbọ́n.
30Èso olódodo ni igi ìyè,
ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.
31Bí a óo bá san ẹ̀san fún olódodo láyé,#1 Pet 4:18
mélòó-mélòó ni ti eniyan burúkú ati ẹlẹ́ṣẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀