ÌWÉ ÒWE 23
23
1Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,
kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára.
2Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra,
kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun.
3Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú,
nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn.
-7-
4Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ,
fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ.
5Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ,
ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò,
bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ.
-8-
6Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun,
má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀;
7nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni.
Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!”
ṣugbọn kò dé inú rẹ̀.
8O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ,
gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù.
-9-
9Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀,
nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ.
-10-
10Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́,
má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba;
11nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára,
yóo gba ìjà wọn jà.
-11-
12Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀.
-12-
13Bá ọmọde wí;
bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú.
14Bí o bá fi pàṣán nà án,
o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú.
-13-
15Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n,
inú mi yóo dùn.
16N óo láyọ̀ ninu ọkàn mi
nígbà tí o bá ń sọ òtítọ́.
-14-
17Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo.
18Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára,
ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.
-15-
19Fetí sí mi, ọmọ mi, kí o sì gbọ́n,
darí ọkàn rẹ sí ọ̀nà títọ́.
20Má bá àwọn ọ̀mùtí kẹ́gbẹ́;
tabi àwọn wọ̀bìà, tí wọn ń jẹ ẹran ní àjẹkì;
21nítorí pé àwọn ọ̀mùtí ati àwọn wọ̀bìà yóo di talaka,
oorun àsùnjù a sì máa sọ eniyan di alákìísà.
-16-
22Gbọ́ ti baba tí ó bí ọ,
má sì ṣe pẹ̀gàn ìyá rẹ nígbà tí àgbà bá dé sí i.
23Ra òtítọ́, má sì tà á,
ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu.
24Baba olódodo ọmọ yóo láyọ̀ pupọ,
inú ẹni tí ó bí ọlọ́gbọ́n ọmọ yóo dùn.
25Mú inú baba ati ìyá rẹ dùn,
jẹ́ kí ìyá tí ó bí ọ láyọ̀ lórí rẹ.
-17-
26Ọmọ mi, gbọ́ tèmi,
kí o sì máa kíyèsí ọ̀nà mi.
27Nítorí aṣẹ́wó dàbí ọ̀fìn jíjìn,
obinrin onírìnkurìn sì dàbí kànga tí ó jìn.
28A máa ba níbùba bí olè,
a sì máa sọ ọpọlọpọ ọkunrin di alágbèrè.
-18-
29Ta ló ni òṣì? Ta ló ni ìbànújẹ́?
Ta ló ni ìjà? Ta ló ni asọ̀?
Ta ló ni ọgbẹ́ láìnídìí? Ta ló ni ojú pípọ́n koko?
30Àwọn tí wọn máa ń pẹ́ ní ìdí ọtí ni,
àwọn tí wọn ń mu ọtí àdàlú.
31Má jẹ́ kí pípọ́n tí ọtí pọ́n fà ọ́ mọ́ra,
nígbà tí ó bá ń ta wínníwínní ninu ife,
tí o dà á mu, tí ó lọ geere lọ́nà ọ̀fun.
32Nígbà tí ó bá yá, á máa buni ṣán bí ejò,
oró rẹ̀ á sì dàbí ti ejò paramọ́lẹ̀.
33Ojú rẹ yóo rí nǹkan àjèjì,
ọkàn rẹ á máa ro èròkerò.
34O óo dàbí ẹni tí ó dùbúlẹ̀ lórí agbami òkun,
bí ẹni tí ó sùn lórí òpó ọkọ̀.
35O óo wí pé, “Wọ́n lù mi, ṣugbọn kò dùn mí;
wọ́n nà mí, ṣugbọn ń kò mọ̀.
Nígbà wo ni n óo tó jí?
N óo tún wá ọtí mìíràn mu.”
-19-
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 23: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010