ÌWÉ ÒWE 24
24
1Má ṣe ìlara àwọn ẹni ibi,
má sì ṣe bá wọn kẹ́gbẹ́,
2nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ìparun,
ẹnu wọn sì ń sọ̀rọ̀ ìkà.
-20-
3Ọgbọ́n ni a fi ń kọ́lé,
òye ni a fi ń fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
4Pẹlu ìmọ̀ ni eniyan fi í kó
oniruuru nǹkan ìní dáradára
olówó iyebíye
kún àwọn yàrá rẹ̀
-21-
5Ọlọ́gbọ́n lágbára ju akọni lọ,
ẹni tí ó ní ìmọ̀ sì ju alágbára lọ.
6Nítorí nípa ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n, o lè jagun,
ọpọlọpọ ìmọ̀ràn níí sìí mú ìṣẹ́gun wà.
-22-
7Ọgbọ́n ga jù fún òmùgọ̀,
kì í lè lanu sọ̀rọ̀ láwùjọ.
-23-
8Ẹni tí ń pète àtiṣe ibi
ni a óo máa pè ní oníṣẹ́ ibi.
9Ẹ̀ṣẹ̀ ni ète òmùgọ̀,
ẹni ìríra sì ni pẹ̀gànpẹ̀gàn.
24
10Bí o bá kùnà lọ́jọ́ ìpọ́njú,
a jẹ́ pé agbára rẹ kò tó.
-25-
11Gba àwọn tí wọ́n bá fẹ́ lọ pa sílẹ̀,
fa àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n,
lọ sọ́dọ̀ àwọn apànìyàn pada.
12Bí ẹ bá sọ pé ẹ kò mọ nǹkan nípa rẹ̀,
ṣé ẹni tí ó mọ èrò ọkàn kò rí i?
Ṣé ẹni tí ń pa ẹ̀mí rẹ mọ́ kò mọ̀,
àbí kò ní san án fún eniyan
gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀?
-26-
13Ọmọ mi, jẹ oyin, nítorí pé ó dùn,
oyin tí a fún láti inú afárá a sì máa dùn lẹ́nu.
14Mọ̀ dájú pé bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n yóo rí fún ọ,
bí o bá ní i, yóo dára fún ọ lẹ́yìn ọ̀la,
ìrètí rẹ kò sì ní di asán.
-27-
15Má lúgọ bí eniyan burúkú láti kó ilé olódodo,
má fọ́ ilé rẹ̀.
16Nítorí pé bí olódodo bá ṣubú léra léra nígbà meje, yóo tún dìde,
ṣugbọn àjálù máa ń bi ẹni ibi ṣubú.
-28-
17Má yọ̀ nígbà tí ọ̀tá rẹ bá ṣubú,
má sì jẹ́ kí inú rẹ dùn bí ó bá kọsẹ̀,
18kí OLUWA má baà bínú sí ọ tí ó bá rí ọ,
kí ó sì yí ojú ibinu rẹ̀ pada kúrò lára ọ̀tá rẹ.
-29-
19Má ṣe kanra nítorí àwọn aṣebi,
má sì ṣe jowú eniyan burúkú,
20nítorí pé kò sí ìrètí fún ẹni ibi,
a óo sì pa àtùpà eniyan burúkú.
-30-
21Ọmọ mi, bẹ̀rù OLUWA ati ọba,
má ṣe àìgbọràn sí ọ̀kankan ninu wọn;
22nítorí jamba lè ti ọ̀dọ̀ wọn wá lójijì,
ta ló mọ irú ìparun, tí ó lè ti ọ̀dọ̀ àwọn mejeeji wá?
Àfikún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́gbọ́n Tẹ̀síwájú sí i
23Àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tún nìwọ̀nyí:
Kò dára láti máa ṣe ojuṣaaju ninu ìdájọ́.
24Ẹni tí ó sọ fún ẹlẹ́ṣẹ̀ pé ọwọ́ rẹ̀ mọ́,
àwọn eniyan yóo gbé e ṣépè,
àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì kórìíra rẹ̀.
25Ṣugbọn yóo dára fún àwọn tí wọ́n bá dá ẹ̀bi fún ẹni tí ó jẹ̀bi,
ibukun Ọlọrun yóo sì bá wọn.
26Ẹni tí ó bá fèsì tí ó tọ́
dàbí ẹni tí ó fi ẹnu koni lẹ́nu.
27Parí iṣẹ́ tí ò ń ṣe níta,
tọ́jú gbogbo nǹkan oko rẹ,
lẹ́yìn náà kọ́ ilé rẹ.
28Má jẹ́rìí lòdì sí aládùúgbò rẹ láìnídìí,
má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ti ẹnu rẹ jáde.
29Má sọ pé, “Bí lágbájá ti ṣe sí mi,
bẹ́ẹ̀ ni èmi náà yóo ṣe sí i,
n óo san ẹ̀san ohun tí ó ṣe fún un.”
30Mo gba ẹ̀gbẹ́ oko ọ̀lẹ kan kọjá,
mo kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà àjàrà ẹnìkan tí kò lóye.
31Wò ó! Ẹ̀gún ti hù níbi gbogbo,
igbó ti bo gbogbo rẹ̀ mọ́lẹ̀,
ọgbà tí ó fi òkúta ṣe yí i ká sì ti wó.
32Mo ṣe àṣàrò lórí ohun tí mo ṣàkíyèsí,
mo sì kọ́ ẹ̀kọ́ lára ohun tí mo rí.
33Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
ìkáwọ́ gbera díẹ̀ láti sinmi,
34bẹ́ẹ̀ ni òṣì yóo ṣe dé bá ọ#Owe 6:10-11
bíi kí olè yọ sí eniyan,
àìní yóo sì wọlé tọ̀ ọ́ bí ẹni tí ó di ihamọra ogun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 24: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010