ÌWÉ ÒWE 5

5
Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè
1Ọmọ mi fetí sí ọgbọ́n tí mò ń kọ́ ọ,
tẹ́tí rẹ sí òye mi,
2kí o baà lè ní làákàyè,
kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè kún fún ìmọ̀.
3Nítorí ẹnu alágbèrè obinrin a máa dùn bí oyin,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì tuni lára ju òróró lọ,
4ṣugbọn níkẹyìn ọ̀rọ̀ rẹ̀ á korò bí iwọ,
ẹnu rẹ̀ á sì mú bí idà olójú meji.
5Ẹsẹ̀ rẹ̀ ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sinu ikú,
ìgbésẹ̀ rẹ̀ sì lọ tààrà sinu ibojì.
6Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè,
ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.
7Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,
ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.
8Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin,
kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀,
9kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn,
kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́.
10Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín,
kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò.
11Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ,
nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni
12nígbà náà ni o óo wí pé,
“Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni,
tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!
13N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi
n kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà.
14Èyí ni ó sún mi dé etí bèbè ìparun,
láàrin àwùjọ eniyan.”
15Ìwọ ọkọ, láti inú àmù rẹ ni kí o ti máa mu omi;
omi tí ń sun láti inú kànga rẹ ni kí o máa mu.
16Kò dára kí orísun rẹ máa ṣàn káàkiri,
bí omi àgbàrá ní gbogbo òpópónà.
17Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́,
má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀.
18Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun,
kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé.
19Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin.
Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo,
kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà.
20Kí ló dé, ọmọ mi,
tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn,
tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin?
21Nítorí OLUWA rí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe,
ó sì ń ṣàkíyèsí gbogbo ìrìn rẹ̀.
22Eniyan burúkú a máa jìn sinu ọ̀fìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
a sì bọ́ sinu ìyọnu nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
23Yóo kú nítorí àìgba ìtọ́ni,
yóo sì sọnù nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌWÉ ÒWE 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀