ÌWÉ ÒWE 6
6
Àwọn Ìkìlọ̀ Mìíràn
1Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,
tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì,
2tí o bá bọ́ sinu tàkúté
tí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ,
tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ,
3o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ.
Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi,
kí o lè gba ara rẹ là:
lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.
4Má sùn,
má sì tòògbé,
5gba ara rẹ sílẹ̀ #Sir 29:14-20
bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ,
àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.
6Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ,
ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n.
7Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ
8sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn;
a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè.
9O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ?
Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun?
10Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,
ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,
11yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. #Owe 24:33-34
Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni.
12Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri,
a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè,
13bí ó ti ń ṣẹ́jú, bẹ́ẹ̀ ni ó ń jansẹ̀ mọ́lẹ̀,
tí ó sì ń fi ìka ṣe àpèjúwe.
14Ó ń fi inú burúkú pète ibi, #Sir 27:22
ó sì ń fi ojoojumọ dá ìjà sílẹ̀,
15nítorí náà, ibi yóo dé bá a lójijì,
yóo parun kíá láìsí àtúnṣe.
16Àwọn nǹkan mẹfa kan wà tí OLUWA kò fẹ́:
wọ́n tilẹ̀ tó meje tí ó jẹ́ ohun ìríra fún un:
17Ìgbéraga, irọ́ pípa,
ẹni tí ń déédé pa aláìṣẹ̀,
18ọkàn tí ń pète ìkà,
ẹsẹ̀ tí ń sáré sí ibi,
19ẹlẹ́rìí èké tí ẹnu rẹ̀ kún fún irọ́,
ati ẹni tí ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin eniyan.
Ìkìlọ̀ nípa Àgbèrè
20Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,
má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.
21Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,
kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.
22Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ,
bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ,
bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀.
23Nítorí fìtílà ni òfin,
ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,
24láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú,
ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀.
25Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́,
má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ.
26Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ,
ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.
27Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà,
kí aṣọ rẹ̀ má jó?
28Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná,
kí iná má jó o lẹ́sẹ̀?
29Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí,
kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà.
30Ẹnìkan kì í kẹ́gàn olè tí ó bá jí oúnjẹ jẹ nítorí ebi.
31Sibẹsibẹ, bí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, yóo fi san ìlọ́po meje,
ó lè jẹ́ pé gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni yóo fi san án.
32Ẹni tí ó bá ṣe àgbèrè kò lọ́gbọ́n lórí,
ẹni tí ó bá dán an wò, ara rẹ̀ ni ó ń parun.
33Ọgbẹ́ ati àbùkù ni yóo gbà,
ìtìjú rẹ̀ kò sì ní kúrò lára rẹ̀ laelae.
34Nítorí owú jíjẹ a máa mú kí inú ọkọ ru,
kò sì ní jẹ́ ṣàánú àlè bó bá di pé à ń gbẹ̀san.
35Kò ní gba owó ìtanràn,
ọpọlọpọ ẹ̀bùn kò sì ní lè tù ú lójú.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌWÉ ÒWE 6: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010

:
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010