ORIN DAFIDI 1

1
ÌWÉ ORIN KINNI
(Orin Dafidi 1–41)
Ayọ̀ Tòótọ́
1Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà
tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,
tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,
tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.
2Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,
a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.
3Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò
tí ń so ní àkókò tí ó yẹ,
tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.
Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere. #Jer 17:8
4Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,
ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.
5Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
6Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,
ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 1: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀