ORIN DAFIDI 103:3-5

ORIN DAFIDI 103:3-5 YCE

ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.