O. Daf 103:3-5
O. Daf 103:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ, Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade: Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì.
O. Daf 103:3-5 Yoruba Bible (YCE)
ẹni tí ó ń dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tí ó ń wo gbogbo àrùn rẹ sàn; ẹni tí ó ń yọ ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ọ̀fìn, tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati àánú dé ọ ládé. Ẹni tí ó ń fi ohun dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn, tí ó fi ń sọ agbára ìgbà èwe rẹ dọ̀tun bíi ti idì.