ORIN DAFIDI 109

109
Ìráhùn Ẹni tí Ó Wà ninu Ìṣòro
1Má dákẹ́, ìwọ Ọlọrun tí mò ń yìn.
2Nítorí pé ẹnu àwọn eniyan burúkú ati ti
àwọn ẹlẹ́tàn kò dákẹ́,
wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké nípa mi.
3Wọ́n ń sọ ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ káàkiri nípa mi,
wọ́n sì ń gbógun tì mí láìnídìí.
4Èmi fẹ́ràn wọn; ṣugbọn ẹ̀sùn ni wọ́n fi ń kàn mí,
sibẹ, adura ni mò ń gbà fún wọn.
5Ibi ni wọ́n fí ń san oore fún mi,
ìkórìíra ni wọ́n sì fi ń san ìfẹ́ tí mo ní sí wọn.
6Yan eniyan burúkú tì í,
jẹ́ kí ẹlẹ́sùn èké kó o sẹ́jọ́.
7Nígbà tí a bá ń dá ẹjọ́ rẹ̀,
jẹ́ kí wọn dá a lẹ́bi;
kí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ di ọ̀ràn sí i lọ́rùn.
8Ṣe é ní ẹlẹ́mìí kúkúrú,
kí ohun ìní rẹ̀ di ti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà.
9Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìníbaba,
kí aya rẹ̀ di opó.
10Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di alárìnká,
kí wọn máa ṣagbe kiri;
kí á lé wọn jáde kúrò ninu ahoro tí wọn ń gbé.
11Kí ẹni tí ó jẹ lówó gba gbogbo ohun ìní rẹ̀,
kí ẹni ẹlẹ́ni sì kó èrè iṣẹ́ rẹ̀.
12Kí ó má bá aláàánú pàdé,
kí ẹnikẹ́ni má sì ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ti di aláìníbaba.
13Kí ìran rẹ̀ run,
kí orúkọ rẹ̀ parẹ́ lórí àwọn ọmọ rẹ̀.
14Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀,
kí ó má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ ìyá rẹ̀ rẹ́.
15Kí OLUWA máa ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn nígbà gbogbo,
kí á má sì ranti ìran wọn mọ́ láyé.#A. Apo 1:20
16Nítorí pé kò ronú láti ṣàánú,
ṣugbọn ó ṣe inúnibíni talaka ati aláìní,
ati sí oníròbìnújẹ́ títí a fi pa wọ́n.
17Ó fẹ́ràn láti máa ṣépè;
nítorí náà kí èpè rẹ̀ dà lé e lórí;
inú rẹ̀ kò dùn sí ìre,
nítorí náà kí ìre jìnnà sí i.
18Ó gbé èpè wọ̀ bí ẹ̀wù,
kí èpè mù ún bí omi,
kí ó sì wọ inú egungun rẹ̀ dé mùdùnmúdùn.
19Kí èpè di aṣọ ìbora fún un,
ati ọ̀já ìgbànú.
20Bẹ́ẹ̀ ni kí OLUWA ṣe sí àwọn ọ̀tá mi,
àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi nípa mi!
21Ṣugbọn, ìwọ OLUWA Ọlọrun mi, gbèjà mi
nítorí orúkọ rẹ, gbà mí!
Nítorí ìfẹ́ rere rẹ tí kì í yẹ̀.
22Nítorí pé talaka ati aláìní ni mí,
ọkàn mí bàjẹ́ lọpọlọpọ.
23Mò ń parẹ́ lọ bí òjìji àṣáálẹ́,
a ti gbọ̀n mí dànù bí eṣú.
24Ẹsẹ̀ mi kò ranlẹ̀ mọ́ nítorí ààwẹ̀ gbígbà,
mo rù kan egungun.
25Mo di ẹni ẹ̀gàn níwájú àwọn ọ̀tá mi,
wọ́n ń wò mí ní àwòmirí.
26Ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, Ọlọrun mi,
gbà mí, nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀.
27Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ni èyí,
kí wọn mọ̀ pé, ìwọ OLUWA ni o ṣe é.
28Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre.
Kí ojú ti àwọn alátakò mi,
kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn.
29Kí ìtìjú bo àwọn ọ̀tá mi bi aṣọ,
àní, kí wọn gbé ìtìjú wọ̀ bí ẹ̀wù.#Mat 27:39; Mak 15:29
30N óo máa fi ẹnu mi yin OLUWA gidigidi,
àní, n óo máa yìn ín ní àwùjọ ọ̀pọ̀ eniyan.
31Nítorí pé ó dúró ti aláìní
láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ó dájọ́ ikú fún un.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 109: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀