ORIN DAFIDI 11

11
OLUWA ni Igbẹkẹle Àwọn Olódodo
1OLUWA ni mo sá di;
ẹ ṣe lè wí fún mi pé,
“Fò lọ sórí òkè bí ẹyẹ;
2ẹ wo àwọn eniyan burúkú bí wọ́n ti kẹ́ ọfà;
wọ́n fa ọrun;
wọ́n sì fi òkùnkùn bojú láti ta olódodo lọ́fà.
3Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́,
kí ni olódodo lè ṣe?”
4OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀,
ìtẹ́ rẹ̀ wà lọ́run;
OLUWA ń kíyèsí àwọn ọmọ eniyan,
ó sì ń yẹ̀ wọ́n wò.
5OLUWA ń yẹ àwọn olódodo, ati eniyan burúkú wò,
ṣugbọn tọkàntọkàn ni ó kórìíra àwọn tí ó fẹ́ràn ìwà ipá.
6Yóo rọ̀jò ẹ̀yinná ati imí ọjọ́ gbígbóná sórí àwọn eniyan burúkú;
ìjì gbígbóná ni yóo sì jẹ́ ìpín wọn.
7Nítorí olódodo ni OLUWA, ó sì fẹ́ràn òdodo;
àwọn olóòótọ́ ni yóo rí ojú rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀