ORIN DAFIDI 115
115
Ọlọrun Òdodo
1Ògo kì í ṣe fún wa, OLUWA, Kì í ṣe fún wa,
orúkọ rẹ nìkan ṣoṣo ni kí á yìn lógo,
nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati nítorí òtítọ́ rẹ.
2Kí ló dé tí àwọn orílẹ̀-èdè yóo fi bèèrè pé,
níbo ni Ọlọrun wa wà?
3Ọlọrun wa wà ní ọ̀run,
ó ń ṣe ohun tí ó wù ú.
4Fadaka ati wúrà ni ère tiwọn,
iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n.
5Wọ́n ní ẹnu, ṣugbọn wọn kò lè sọ̀rọ̀,
wọ́n lójú, ṣugbọn wọn kò ríran.
6Wọ́n létí, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn,
wọ́n nímú, ṣugbọn wọn kò gbóòórùn.
7Wọ́n lọ́wọ́, ṣugbọn wọn kò lè lò ó,
wọ́n lẹ́sẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè rìn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè gbin.
8Àwọn tí ó ń yá àwọn ère náà dàbí wọn,
bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé wọn.#O. Daf 135:15-18; Jer 4:73; Ifi 9:20
9Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,
òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.
10Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,
òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.
11Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLUWA, ẹ gbẹ́kẹ̀lé e,
òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.
12OLUWA ranti wa, yóo bukun wa,
yóo bukun ilé Israẹli,
yóo bukun ìdílé Aaroni.
13Yóo bukun àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
ati àwọn ọlọ́lá ati àwọn mẹ̀kúnnù.#Ifi 11:18; 19:5
14OLUWA yóo jẹ́ kí ẹ máa bí sí i,
àtẹ̀yin àtàwọn ọmọ yín.
15Kí OLUWA tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun yín!
16OLUWA ló ni ọ̀run,
ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan.
17Àwọn òkú kò lè yin OLUWA,
àní àwọn tí wọ́n ti dákẹ́ ninu ibojì.
18Ṣugbọn àwa yóo máa yin OLUWA,
láti ìsinsìnyìí lọ, ati títí laelae.
Ẹ máa yin OLUWA.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 115: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010