ORIN DAFIDI 118
118
Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun
1Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.#1Kron 16:34; 2Kron 5:13; 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 100:5; 106:1; 107:1; 136:1; Jer 33:11
2Jẹ́ kí Israẹli wí pé,
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”
3Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé,
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”
4Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé,
“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”
5Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA,
ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀.
6Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí.
Kí ni eniyan lè fi mí ṣe?
7OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́,
nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mi
pẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun.
8Ó sàn láti sá di OLUWA,
ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ.
9Ó sàn láti sá di OLUWA,
ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè.#Heb 13:6
10Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi,
ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!
11Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi,
ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!
12Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin,
ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́;
ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run.
13Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú,
ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́.
14OLUWA ni agbára ati orin mi,
ó ti di olùgbàlà mi.#Eks 15:2; Ais 12:2
15Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,
ninu àgọ́ àwọn olódodo.
“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.
16A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,
ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!”
17N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,
n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe.
18OLUWA jẹ mí níyà pupọ,
ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.
19Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,
kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,
kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA.
20Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;
àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé.
21Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,
o sì ti di olùgbàlà mi.
22Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,
ni ó di pataki igun ilé.
23OLUWA ló ṣe èyí;
ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.
24Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,
ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.
25OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,
OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.#Luk 20:17; A. Apo 4:11; 1 Pet 2:7 #Mat 21:42; Mak 12:10-11 #Mat 21:9; Mak 11:9; Joh 12:13
26Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,
láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.
27OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.
Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,
títí dé ibi ìwo pẹpẹ.#Mat 21:9; 23:39; Mak 11:9; Luk 13:35; 19:38; Joh 12:13
28Ìwọ ni Ọlọrun mi,
n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.
Ìwọ ni Ọlọrun mi,
n óo máa gbé ọ ga.
29Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,
nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 118: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010