ORIN DAFIDI 123

123
Adura Àánú
1Ìwọ ni mo gbé ojú sókè sí,
ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run.
2Wò ó, bí iranṣẹkunrin ti máa ń wo ojú oluwa rẹ̀,
tí iranṣẹbinrin sì máa ń wo ojú oluwa rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni à ń wo ojú OLUWA, Ọlọrun wa,
títí tí yóo fi ṣàánú wa.
3Ṣàánú wa, OLUWA, ṣàánú wa,
ẹ̀gàn yìí ti pọ̀ jù!
4Ẹ̀gàn àwọn onírera ti pọ̀ jù fún wa;
yẹ̀yẹ́ àwọn onigbeeraga sì ti sú wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 123: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀