ORIN DAFIDI 13

13
Adura Ìrànlọ́wọ́
1Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA?
Ṣé o óo wá gbàgbé mi laelae ni?
Títí di ìgbà wo ni o óo fi ojú pamọ́ fún mi?
2Títí di ìgbà wo ni ọkàn mi yóo gbọgbẹ́
tí ìbànújẹ́ yóo gba ọkàn mi kan, ní gbogbo ìgbà?
Títí di ìgbà wo ni àwọn ọ̀tá mi yóo máa yọ̀ mí?
3Bojúwò mí, kí o sì dá mi lóhùn, OLUWA, Ọlọrun mi.
Tan ìmọ́lẹ̀ sí ojú mi, kí n má baà sun oorun ikú.
4Kí ọ̀tá mi má baà wí pé, “Mo ti rẹ́yìn rẹ̀.”
Kí àwọn tí ó kórìíra mi má baà yọ̀ bí mo bá ṣubú.
5Ṣùgbọ́n èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀;
n óo máa yọ̀ nítorí pé o óo gbà mí.
6N óo máa kọrin sí ọ, OLUWA,
nítorí o ṣeun fún mi lọpọlọpọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 13: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀