ORIN DAFIDI 133
133
Ìrẹ́pọ̀ Àwọn ará
1Ó dára, ó sì dùn pupọ,
bí àwọn ará bá ń gbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀.
2Ó dàbí òróró iyebíye tí a dà síni lórí,
tí ó ṣàn dé irùngbọ̀n;
bí ó ti ṣàn dé irùngbọ̀n Aaroni,
àní, títí dé ọrùn ẹ̀wù rẹ̀.
3Ó dàbí ìrì òkè Herimoni,
tí ó sẹ̀ sórí òkè Sioni.
Níbẹ̀ ni OLUWA ti ṣe ìlérí ibukun,
àní, ìyè ainipẹkun.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 133: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010