ORIN DAFIDI 143

143
Adura Ìrànlọ́wọ́
1OLUWA, gbọ́ adura mi;
fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi!
Dá mi lóhùn ninu òtítọ́ ati òdodo rẹ.
2Má dá èmi ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lẹ́jọ́,
nítorí pé kò sí ẹ̀dá alààyè tí ẹjọ́ rẹ̀ lè tọ́ níwájú rẹ.#Rom 3:20; Gal 2:16
3Ọ̀tá ti lé mi bá,
ó ti lù mí bolẹ̀;
ó jù mí sinu òkùnkùn,
bí ẹni tí ó ti kú tipẹ́tipẹ́.
4Nítorí náà ọkàn mi rẹ̀wẹ̀sì;
ọkàn mi sì pòrúúruù.
5Mo ranti ìgbà àtijọ́,
mo ṣe àṣàrò lórí gbogbo ohun tí o ti ṣe,
mo sì ronú lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
6Mo na ọwọ́ sí ọ fún ìrànlọ́wọ́;
bí òùngbẹ omi í tií gbẹ ilẹ̀ gbígbẹ,
bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi.
7OLUWA, yára dá mi lóhùn!
Ẹ̀mí mi ti fẹ́rẹ̀ pin!
Má fara pamọ́ fún mi,
kí n má baà dàbí àwọn tí ó ti lọ sinu isà òkú.
8Jẹ́ kí n máa ranti ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ láràárọ̀,
nítorí ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.
Kọ́ mi ní ọ̀nà tí n óo máa rìn,
nítorí pé ìwọ ni mo gbójú sókè sí.
9OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi;
ìwọ ni mo sá di.
10Kọ́ mi láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ,
nítorí pé ìwọ ni Ọlọrun mi.
Jẹ́ kí ẹ̀mí rere rẹ máa tọ́ mi ní ọ̀nà tí ó tọ́.
11Nítorí ti orúkọ rẹ, OLUWA, dá mi sí;
ninu òtítọ́ rẹ, yọ mí ninu ìpọ́njú.
12Ninu ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, pa àwọn ọ̀tá mi,
kí o sì pa gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi run,
nítorí pé iranṣẹ rẹ ni mí.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 143: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀