ORIN DAFIDI 16

16
Mo Sá di OLUWA
1Pa mí mọ́ Ọlọrun, nítorí ìwọ ni mo sá di.
2Mo wí fún ọ, OLUWA, pé, “Ìwọ ni Oluwa mi;
ìwọ nìkan ni orísun ire mi.”
3Nípa àwọn eniyan mímọ́ tí ó wà nílẹ̀ yìí,
wọ́n jẹ́ ọlọ́lá tí àwọn eniyan fẹ́ràn.#16:3 Ìtumọ̀ ẹsẹ kẹta yìí kò yéni ninu Bibeli èdè Heberu.
4“Ìbànújẹ́ àwọn tí ń sá tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn yóo pọ̀:
Èmi kò ní bá wọn ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ fún ìrúbọ,
bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò ní gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu mi.”
5OLUWA, ìwọ ni ìpín mi, ìwọ ni mo yàn;
ìwọ ni ò ń jẹ́ kí ọ̀ràn mi fìdí múlẹ̀.
6Ìpín tí ó bọ́ sí mi lọ́wọ́ dára pupọ;
ogún rere ni ogún ti mo jẹ.
7Èmi óo máa yin OLUWA, ẹni tí ó ń fún mi ní òye;
ọkàn mi ó sì máa tọ́ mi sọ́nà ní òròòru.
8Mò ń wo OLUWA ní iwájú mi nígbà gbogbo,
nítorí pé Ọlọrun dúró tì mí, ẹsẹ̀ mi kò ní yẹ̀.
9Nítorí náà ni ọkàn mi ṣe ń yọ̀, tí inú mi dùn;
ara sì rọ̀ mí.
10Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú,
bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́.#A. Apo 13:35
11O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí;
ayọ̀ kíkún ń bẹ ní iwájú rẹ,
ìgbádùn àìlópin sì ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.#A. Apo 2:25-28

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀