ORIN DAFIDI 17

17
Adura fún Ìdáláre
1Gbọ́ tèmi OLUWA, àre ni ẹjọ́ mi;#17:1 Àwọn Bibeli mìíràn kà báyìí pé: “Gbọ́ tèmi, OLUWA, olódodo ni mí.”
fi ìtara gbọ́ igbe mi.
Fetí sí adura mi nítorí kò sí ẹ̀tàn ní ẹnu mi.
2Jẹ́ kí ìdáláre mi ti ọ̀dọ̀ rẹ wá;
kí o sì rí i pé ẹjọ́ mi tọ́.
3Yẹ ọkàn mi wò; bẹ̀ mí wò lóru.
Dán mi wò, o kò ní rí ohun burúkú kan;
n kò ní fi ẹnu mi dẹ́ṣẹ̀.
4Nítorí ohun tí o wí nípa èrè iṣẹ́ ọwọ́ eniyan,
mo ti yàgò fún àwọn oníwà ipá.
5Mò ń tọ ọ̀nà rẹ tààrà;
ẹsẹ̀ mi kò sì yọ̀.
6Mo ké pè ọ́, dájúdájú ìwọ Ọlọrun yóo dá mi lóhùn,
dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.
7Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn lọ́nà ìyanu,
fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ
kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ó gbógun tì wọ́n.
8Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú,
dáàbò bò mí lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ;
9lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú tí ó gbé ìjà kò mí,
àní lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.
10Ojú àánú wọn ti fọ́,
ọ̀rọ̀ ìgbéraga sì ń ti ẹnu wọn jáde.
11Wọn ń lépa mi; wọ́n sì ti yí mi ká báyìí;
wọn ń ṣọ́ bí wọn ó ṣe bì mí ṣubú.
12Wọ́n dàbí kinniun tí ó ṣetán láti pa ẹran jẹ,
àní bí ọmọ kinniun tí ó ba ní ibùba.
13Dìde, OLUWA! Dojú kọ wọ́n; là wọ́n mọ́lẹ̀;
fi idà rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú.
14OLUWA, fi ọwọ́ ara rẹ gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan wọnyi;
àwọn tí ìpín wọn jẹ́ ohun ti ayé yìí,
fi ohun rere jíǹkí àwọn ẹni tí o pamọ́;
jẹ́ kí àwọn ọmọ jẹ àjẹyó;
sì jẹ́ kí àwọn ọmọ ọmọ wọn rí ogún wọn jẹ.#17:14 Ìtumọ̀ ẹsẹ kẹrinla kò yéni yékéyéké ninu Bibeli èdè Heberu .
15Ní tèmi, èmi óo rí ojú rẹ nítorí òdodo mi,
ìrísí rẹ yóo sì tẹ́ mi lọ́rùn nígbà tí mo bá jí.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 17: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀