ORIN DAFIDI 21

21
Orin Ìṣẹ́gun
1Ọba ń yọ̀ nítorí agbára rẹ, OLUWA;
inú rẹ̀ ń dùn lọpọlọpọ nítorí ríràn tí o ràn án lọ́wọ́!
2O ti fún un ní ohun tí ọkàn rẹ̀ ń fẹ́,
o kò sì fi ohun tí ó ń tọrọ dù ú.
3O gbé ibukun dáradára pàdé rẹ̀;
o fi adé ojúlówó wúrà dé e lórí.
4Ó bèèrè ẹ̀mí gígùn lọ́wọ́ rẹ; o fi fún un,
àní, ọjọ́ gbọọrọ títí ayé.
5Òkìkí rẹ̀ pọ̀ nítorí pé o ràn án lọ́wọ́;
o sì fi iyì ati ọlá ńlá jíǹkí rẹ̀.
6Nítòótọ́ o sọ ọ́ di ẹni ibukun títí lae;
o sì mú kí inú rẹ̀ dùn nítorí pé o wà pẹlu rẹ̀.
7Nítorí pé ọba gbẹ́kẹ̀lé OLUWA;
a kò ní ṣí i ní ipò pada,
nítorí ìfẹ́ Ọ̀gá Ògo tí kì í yẹ̀.
8Ọwọ́ rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóo tẹ gbogbo àwọn tí ó kórìíra rẹ.
9O óo jó wọn run bí iná ìléru, nígbà tí o bá yọ sí wọn.
OLUWA yóo gbé wọn mì ninu ibinu rẹ̀;
iná yóo sì jó wọn ní àjórun.
10O óo pa àwọn ọmọ wọn run lórí ilẹ̀ ayé,
o óo sì run ìran wọn láàrin àwọn eniyan.
11Bí wọn bá gbèrò ibi sí ọ,
tí wọ́n sì pète ìkà, wọn kò ní lè ṣe é.
12Nítorí pé o óo lé wọn sá;
nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn.
13A gbé ọ ga, nítorí agbára rẹ, OLUWA!
A óo máa kọrin, a óo sì máa yin agbára rẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 21: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀