ORIN DAFIDI 29

29
Agbára OLUWA ninu ìjì
1Ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run, ẹ fi ògo fún OLUWA,
ẹ gbé agbára rẹ̀ lárugẹ.
2Ẹ fún OLUWA ní ògo tí ó yẹ orúkọ rẹ̀,
ẹ máa sin OLUWA ninu ẹwà mímọ́ rẹ̀.#O. Daf 96:7-9
3À ń gbọ́ ohùn OLUWA lójú omi òkun,
Ọlọrun ológo ń sán ààrá,
Ọlọrun ń sán ààrá lójú alagbalúgbú omi.
4Ohùn OLUWA lágbára,
ohùn OLUWA kún fún ọlá ńlá.
5Ohùn OLUWA ń fọ́ igi kedari,
OLUWA ń fọ́ igi kedari ti Lẹbanoni.
6Ó ń mú kí òkè Lẹbanoni ta pọ́núnpọ́nún bí ọmọ mààlúù,
ó sì mú kí òkè Sirioni máa fò bí akọ ọmọ mààlúù-igbó.
7Ohùn OLUWA ń yọ iná lálá.
8Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀;
OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi.
9Ohùn OLUWA a máa mú abo àgbọ̀nrín bí,
a máa wọ́ ewé lára igi oko;
gbogbo eniyan ń kígbe ògo rẹ̀ ninu Tẹmpili rẹ̀.
10OLUWA jókòó, ó gúnwà lórí ìkún omi;
OLUWA jókòó, ó gúnwà bí ọba títí lae.
11OLUWA yóo fún àwọn eniyan rẹ̀ ní agbára;
OLUWA yóo fún wọn ní ibukun alaafia.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 29: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀