ORIN DAFIDI 3

3
Adura ìrànlọ́wọ́ lówùúrọ̀ #2Sam 15:13–17:22
1OLUWA, àwọn ọ̀tá mi pọ̀ pupọ!
Ọ̀pọ̀ ni ó ń dìde sí mi!
2Ọpọlọpọ ni àwọn tí ń sọ kiri pé,
Ọlọrun kò ní gbà mí sílẹ̀!
3Ṣugbọn ìwọ OLUWA ni ààbò mi,
ògo mi, ati ẹni tí ó fún mi ní ìgboyà.
4Mo ké pe OLUWA,
ó sì dá mi lóhùn láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá.
5Mo dùbúlẹ̀, mo sùn, mo sì jí,
nítorí OLUWA ni ó ń gbé mi ró.
6Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀tá tó yí mi ká
kò le bà mí lẹ́rù.
7Dìde, OLUWA, gbà mí, Ọlọrun mi!
Nítorí ìwọ ni o lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi bolẹ̀,
tí o sì ṣẹgun àwọn eniyan burúkú.
8OLUWA níí gbani,
kí ibukun rẹ̀ kí ó wà lórí àwọn eniyan rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 3: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀