ORIN DAFIDI 38
38
Adura Ẹni tí Ìyà ń Jẹ
1OLUWA, má fi ibinu bá mi wí!
Má sì fi ìrúnú jẹ mí níyà!
2Nítorí pé ọfà rẹ ti wọ̀ mí lára,
ọwọ́ rẹ sì ti bà mí.
3Kò sí ibìkan tí ó gbádùn ní gbogbo ara mi
nítorí ibinu rẹ;
kò sì sí alaafia ninu gbogbo egungun mi,
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti bò mí lórí mọ́lẹ̀;
ó rìn mí mọ́lẹ̀ bí ẹrù ńlá
tí ó wúwo jù fún mi.
5Ọgbẹ́ mi ń kẹ̀, ó sì ń rùn,
nítorí ìwà òmùgọ̀ mi,
6Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,
mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru.
7Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,
kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi.
8Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;
mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi.
9OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,
ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ.
10Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá;
ojú mi sì ti di bàìbàì.
11Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi,
àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré.
12Àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí mi dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,
àwọn tí ń wá ìpalára mi ń sọ̀rọ̀ ìparun mi,
wọ́n sì ń pète àrékérekè tọ̀sán-tòru.
13Ṣugbọn mo ṣe bí adití, n kò gbọ́,
mo dàbí odi tí kò le sọ̀rọ̀.
14Àní, mo dàbí ẹni tí kò gbọ́rọ̀,
tí kò sì ní àwíjàre kan lẹ́nu.
15Ṣugbọn, OLUWA, ìwọ ni mò ń dúró dè;
OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni o óo dá mi lóhùn.
16Nítorí tí mò ń gbadura pé,
kí àwọn tí ń pẹ̀gàn mi má yọ̀ mí
nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yẹ̀.
17Nítorí pé mo ti fẹ́rẹ̀ ṣubú,
mo sì wà ninu ìrora nígbà gbogbo.
18Mo jẹ́wọ́ àṣìṣe mi,
mo sì káàánú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19Àwọn tí ń bá mi ṣọ̀tá láìnídìí lágbára,
àwọn tí ó kórìíra mi láìtọ́ sì pọ̀.
20Àwọn tí ń fi ibi san oore fún mi ní ń gbógun tì mí,
nítorí pé rere ni mò ń ṣe.
21OLUWA, má kọ̀ mí sílẹ̀,
Ọlọrun mi, má jìnnà sí mi.
22Yára wá ràn mí lọ́wọ́, OLUWA, ìgbàlà mi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 38: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010