ORIN DAFIDI 46
46
Ọlọrun Wà pẹlu Wa
1Ọlọrun ni ààbò ati agbára wa,
olùrànlọ́wọ́ tí ó wà nítòsí nígbà gbogbo, ní ìgbà ìpọ́njú.
2Nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà wá bí ayé tilẹ̀ ṣídìí,
bí àwọn òkè ńlá tilẹ̀ ṣípò pada, tí wọ́n bọ́ sinu òkun;
3bí omi òkun tilẹ̀ ń hó, tí ó sì ń ru,
tí àwọn òkè ńlá sì ń mì tìtì
nítorí agbára ríru rẹ̀.
4Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn,
ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo.
5Ọlọrun wà láàrin rẹ̀,
kò ní tú bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣí kúrò;
Ọlọrun yóo ràn án lọ́wọ́ ní òwúrọ̀ kutukutu.
6Inú àwọn orílẹ̀-èdè ń ru,
àwọn ìjọba ayé ń gbọ̀n;
OLUWA fọhùn, ayé sì yọ́.
7OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa;
Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.
8Ẹ wá wo iṣẹ́ OLUWA,
irú iṣẹ́ ribiribi tí ó ṣe láyé.
9Ó dáwọ́ ogun dúró ní gbogbo ayé,
ó ṣẹ́ ọrun, ó rún ọ̀kọ̀,
ó dáná sun kẹ̀kẹ́ ogun.
10“Ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni Ọlọrun.
A gbé mi ga láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,
a gbé mi ga ní ayé.”
11OLUWA àwọn ọmọ ogun wà pẹlu wa,
Ọlọrun Jakọbu ni ààbò wa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 46: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010