ORIN DAFIDI 5

5
Adura Ààbò
1Fetí sí ọ̀rọ̀ mi, OLUWA;
kíyèsí ìmí ẹ̀dùn mi.
2Fetí sí igbe mi,
Ọba mi ati Ọlọrun mi,
nítorí ìwọ ni mò ń gbadura sí.
3OLUWA, o óo gbọ́ ohùn mi ní òwúrọ̀,
ní òwúrọ̀ ni n óo máa sọ ẹ̀dùn ọkàn mi fún ọ;
èmi óo sì máa ṣọ́nà.
4Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọrun tí inú rẹ̀ dùn sí ìwà burúkú;
àwọn ẹni ibi kò sì lè bá ọ gbé.
5Àwọn tí ń fọ́nnu kò lè dúró níwájú rẹ;
o kórìíra gbogbo àwọn aṣebi.
6O máa ń pa àwọn òpùrọ́ run;
OLUWA, o kórìíra àwọn apani ati ẹlẹ́tàn.
7Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,
èmi óo wọ inú ilé rẹ;
n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ.
8OLUWA, tọ́ mi sọ́nà òdodo rẹ, nítorí àwọn ọ̀tá mi;
jẹ́ kí ọ̀nà rẹ hàn kedere níwájú mi.
9Nítorí kò sí òtítọ́ kan lẹ́nu wọn;
ìparun ni ó wà ninu ọkàn wọn.
Isà òkú tí ó yanu sílẹ̀ ni ọ̀fun wọn;
ẹnu wọn kún fún ìpọ́nni ẹ̀tàn.
10Dá wọn lẹ́bi, Ọlọrun, kí o sì fìyà jẹ wọ́n;
jẹ́ kí ìgbìmọ̀pọ̀ wọn ó gbé wọn ṣubú.
Ta wọ́n nù nítorí ọ̀pọ̀ ìrékọjá wọn,
nítorí pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.#Rom 3:13
11Ṣugbọn jẹ́ kí inú gbogbo àwọn tí ó sá di ọ́ ó dùn,
kí wọn ó máa kọrin ayọ̀ títí lae.
Dáàbò bò wọ́n,
kí àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ sì máa yọ̀ ninu rẹ.
12Nítorí ìwọ OLUWA a máa bukun àwọn olódodo;
ò sì máa fi ojurere rẹ tí ó dàbí apata dáàbò bò wọ́n.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀