ORIN DAFIDI 63

63
Wíwá Ọlọrun#1Sam 23:14
1Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ,
ọkàn rẹ ń fà mí;
bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹ
ṣe máa ń kóǹgbẹ omi.
2Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ,
mo ti rí agbára ati ògo rẹ.
3Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ,
n óo máa yìn ọ́.
4N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi;
n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ.
5Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù;
n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.
6Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,
tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru;
7nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,
lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin.
8Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ;
ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró.
9Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi
yóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú.
10A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun,
ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn.
11Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun;
gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búra
yóo máa fògo fún un;
ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 63: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀