ORIN DAFIDI 70
70
Adura Ìrànlọ́wọ́
1Ọlọrun, dákun, gbà mí,
yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.
2Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọn fẹ́ gba ẹ̀mí mi
kí ìdàrúdàpọ̀ bá wọn;
jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,
kí wọn sì tẹ́.
3Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bo
àwọn tí ń yọ̀ mí, tí ń ṣe jàgínní mi;
kí wọn sì gba èrè ìtìjú.
4Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀ nítorí rẹ,
kí inú wọn sì máa dùn,
kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹ máa wí nígbà gbogbo pé,
“Ọlọrun tóbi!”
5Ṣugbọn ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí,
yára wá sọ́dọ̀ mi, Ọlọrun!
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi ati olùgbàlà mi,
má pẹ́ OLÚWA.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 70: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010