ORIN DAFIDI 8

8
Ògo OLUWA ati Ipò Eniyan
1OLUWA, Oluwa wa,
orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!
Ìwọ ni o gbé ògo rẹ kalẹ̀ lókè ọ̀run.
2Àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ń kọrin ògo rẹ,
wọ́n ti fi ìdí agbára rẹ múlẹ̀,
nítorí àwọn tí ó kórìíra rẹ,
kí á lè pa àwọn ọ̀tá ati olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.#Mat 21:16
3Nígbà tí mo ṣe akiyesi ojú ọ̀run, iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, tí o sọlọ́jọ̀–
4Kí ni eniyan jẹ́, tí o fi n náání rẹ̀?
Àní, kí ni ọmọ eniyan, tí o fi ń ṣìkẹ́ rẹ̀?#Job 7:17-18; O. Daf 144:3; Heb 2:6-8
5O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ sí ti ìwọ Ọlọrun,
o sì ti fi ògo ati ọlá dé e ní adé.
6O mú un jọba lórí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,
o sì fi gbogbo nǹkan sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:#1 Kọr 15:27; Efe 1:22; Heb 2:8
7àwọn aguntan, ati àwọn mààlúù, ati gbogbo ẹranko ninu igbó;
8àwọn ẹyẹ ojú ọrun, àwọn ẹja inú òkun,
ati gbogbo nǹkan tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ ninu òkun.
9OLUWA, Oluwa wa,
orúkọ rẹ níyìn pupọ ní gbogbo ayé!

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ORIN DAFIDI 8: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀