ORIN DAFIDI 95
95
Orin Ìyìn
1Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọrin sí OLUWA;
ẹ jẹ́ kí á hó ìhó ayọ̀ sí Olùdáàbòbò ati ìgbàlà wa!
2Ẹ jẹ́ kí á wá siwaju rẹ̀ pẹlu ọpẹ́;
ẹ jẹ́ kí á fi orin ìyìn hó ìhó ayọ̀ sí i.
3Nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi ni OLUWA,
ọba tí ó tóbi ni, ó ju gbogbo oriṣa lọ.
4Ìkáwọ́ rẹ̀ ni ọ̀gbun ilẹ̀ wà;
gíga àwọn òkè ńlá wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pẹlu.
5Tirẹ̀ ni òkun, nítorí pé òun ni ó dá a;
ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi dá ìyàngbẹ ilẹ̀.
6Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba,
ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!
7Nítorí òun ni Ọlọrun wa,
àwa ni eniyan rẹ̀, tí ó ń kó jẹ̀ káàkiri,
àwa ni agbo aguntan rẹ̀.
Ọlọrun Bá Àwọn Eniyan Rẹ̀ sọ̀rọ̀
Bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀ lónìí,
8ẹ má ṣe orí kunkun bí ẹ ti ṣe ní Meriba,
ati bí ẹ ti ṣe ní ijọ́un ní Masa, ninu aṣálẹ̀#Heb 3:15; 4:7
9nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò,
tí wọ́n dẹ mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí
ohun tí mo ti ṣe rí.#Eks 17:1-7; Nọm 20:2-13
10Fún ogoji ọdún gbáko ni ọ̀rọ̀ wọn fi sú mi,
tí mo sọ pé, “Ọkàn àwọn eniyan wọnyi ti yapa,
wọn kò sì bìkítà fún ìlànà mi.”
11Nítorí náà ni mo fi fi ibinu búra pé,
wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.#Heb 3:7-11 #(a) Nọm 14:20-23; Diut 1:34-36; Heb 4:3-5 (b) Diut 12:9-10
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ORIN DAFIDI 95: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010