ÌFIHÀN 1
1
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju ati Ìkíni
1Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó níláti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ nìyí, tí Ọlọrun fún Jesu Kristi, pé kí ó fihan àwọn iranṣẹ rẹ̀. Jesu wá rán angẹli rẹ̀ sí Johanu, iranṣẹ rẹ̀, pé kí ó fi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà hàn án. 2Johanu sọ gbogbo nǹkan tí ó rí nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹ̀rí Jesu Kristi. 3Ẹni tí ó bá ń ka ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ati àwọn tí ó bá ń gbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tí a kọ, ṣe oríire. Nítorí àkókò tí yóo ṣẹlẹ̀ súnmọ́ tòsí.
4Èmi Johanu ni mo ranṣẹ sí ìjọ meje tí ó wà ní agbègbè Esia.
Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia wà pẹlu yín láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti wà, tí ó ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, ati láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí meje tí wọ́n wà níwájú ìtẹ́ rẹ̀; #a Eks 3:14; b Ifi 4:5 5ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé.
Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa. #a Ais 55:4; b O. Daf 89:27 6Ó sọ wá di ìjọba, ati alufaa Ọlọrun Baba rẹ̀. Tirẹ̀ ni ògo ati agbára lae ati laelae. Amin. #Eks 19:6; Ifi 5:10
7Wò ó! Ó ń bọ̀ ninu awọsanma, gbogbo eniyan ni yóo sì rí i. Àwọn tí wọ́n gún un lọ́kọ̀ náà yóo rí i. Gbogbo ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóo dárò nígbà tí wọ́n bá rí i. Amin! Àṣẹ! #a Dan 7:13; Mat 24:30; Mak 13:26, Luk 21:27; 1 Tẹs 4:17; b Sek 12:10; Joh 19:34,37; d Sek 12:10, Mat 24:30
8“Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin.” Oluwa Ọlọrun ló sọ bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó ti wà, tí ń bẹ, tí ó sì tún ń bọ̀ wá, Olodumare. #a Ifi 22:13; b Eks 3:14
Ìran Kristi
9Èmi ni Johanu, arakunrin yín ati alábàápín pẹlu yín ninu ìpọ́njú tí ẹni tí ó bá tẹ̀lé Jesu níláti rí, ati ìfaradà tí ó níláti ní. Wọ́n jù mí sí ilẹ̀ kan tí ń jẹ́ Patimosi nítorí mo waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun, mo sì jẹ́rìí pé Jesu ni mo gbàgbọ́. Erékùṣù ni ilẹ̀ Patimosi, ó wà láàrin omi. 10Nígbà tí ó di Ọjọ́ Oluwa, ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi bí ìgbà tí fèrè bá ń dún, 11ó ní, “Kọ ohun tí o bá rí sinu ìwé, kí o fi ranṣẹ sí àwọn ìjọ ní ìlú mejeeje wọnyi: Efesu ati Simana, Pẹgamu ati Tiatira, Sadi ati Filadẹfia ati Laodikia.”
12Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje. 13Ní ààrin àwọn ọ̀pá fìtílà yìí ni ẹnìkan wà tí ó dàbí eniyan. Ó wọ ẹ̀wù tí ó balẹ̀ dé ilẹ̀. Ó fi ọ̀já wúrà gba àyà. #a Dan 7:13 b Dan 10:5 14Irun orí rẹ̀ funfun gbòò bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Ojú rẹ̀ ń kọ yànràn bí iná. #Dan 7:9 15Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ tí ń dán, tí alágbẹ̀dẹ ń dà ninu iná. Ohùn rẹ̀ dàbí híhó omi òkun. #Dan 10:6 #Isi 1:24; 43:2 16Ó mú ìràwọ̀ meje lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀. Idà olójú meji tí ó mú yọ jáde lẹ́nu rẹ̀. Ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀ bí oòrùn ọ̀sán gangan. 17Nígbà tí mo rí i, mo ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó bá gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi. Ó ní, “Má bẹ̀rù. Èmi ni ẹni kinni ati ẹni ìkẹyìn. #Ais 44:6; 48:12; Ifi 2:8; 22:13 18Èmi ni ẹni tí ó wà láàyè. Mo kú, ṣugbọn mo ti jí, mo sì wà láàyè lae ati laelae. Àwọn kọ́kọ́rọ́ ikú ati ti ipò òkú wà lọ́wọ́ mi. 19Nítorí náà kọ àwọn ohun tí o rí sílẹ̀, ati àwọn ohun tí ó wà nisinsinyii ati àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la. 20Àṣírí ìràwọ̀ meje tí o rí ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ati ti ọ̀pá fìtílà wúrà meje nìyí: ìràwọ̀ meje ni àwọn angẹli ìjọ meje. Ọ̀pá fìtílà meje ni àwọn ìjọ meje.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌFIHÀN 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010