ÌFIHÀN 12:5-6

ÌFIHÀN 12:5-6 YCE

Obinrin yìí bí ọmọkunrin, tí yóo jọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè pẹlu ọ̀pá irin. A bá já ọmọ náà gbà lọ sọ́dọ̀ Ọlọrun, níwájú ìtẹ́ rẹ̀. Obinrin yìí bá sálọ sí aṣálẹ̀, níbìkan tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀. Níbẹ̀ ni ó wà lábẹ́ ìtọ́jú fún ẹgbẹfa ọjọ́ ó lé ọgọta (1260).