ÌFIHÀN 17
17
Babiloni Ìlú Ńlá, Gbajúmọ̀ Àgbèrè
1Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi.#Jer 51:13 2Àwọn ọba ayé ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀, àwọn tí ń gbé inú ayé ti mu ninu ọtí àgbèrè rẹ̀.”#Ais 23:17; Jer 51:7
3Ẹ̀mí gbé mi, ni angẹli yìí bá gbé mi lọ sinu aṣálẹ̀. Níbẹ̀ ni mo ti rí obinrin tí ó gun ẹranko pupa kan, tí àwọn orúkọ àfojúdi kún ara rẹ̀. Ẹranko náà ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá.#Ifi 13:1 4Aṣọ àlàárì ati aṣọ pupa ni obinrin náà wọ̀. Ó fi ọ̀ṣọ́ wúrà sára pẹlu oríṣìíríṣìí ìlẹ̀kẹ̀ olówó iyebíye. Ó mú ife wúrà lọ́wọ́, ife yìí kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìbàjẹ́ àgbèrè rẹ̀.#Jer 51:7 5Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.” 6Mo wá rí obinrin náà tí ó ti mu ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan Ọlọrun ní àmuyó, pẹlu ẹ̀jẹ̀ àwọn tí wọ́n jẹ́rìí igbagbọ ninu Jesu.
Ìyanu ńlá ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí obinrin náà. 7Angẹli náà bi mí pé, “Kí ni ó yà ọ́ lẹ́nu? N óo sọ àṣírí obinrin náà fún ọ ati ti ẹranko tí ó gùn, tí ó ní orí meje ati ìwo mẹ́wàá. 8Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.#a Dan 7:7; Ifi 11:7 b O. Daf 69:28
9“Ọ̀rọ̀ yìí gba ọgbọ́n. Orí meje tí ẹranko náà ní jẹ́ òkè meje tí obinrin náà jókòó lé lórí. Wọ́n tún jẹ́ ọba meje. 10Marun-un ninu wọn ti kú. Ọ̀kan wà lórí oyè nisinsinyii. Ọ̀kan yòókù kò ì tíì jẹ. Nígbà tí ó bá jọba, àkókò díẹ̀ ni yóo ṣe lórí oyè. 11Ẹranko tí ó ti wà láàyè rí, tí kò sí mọ́, ni ẹkẹjọ, ṣugbọn ó wà ninu àwọn meje tí ń lọ sinu ègbé.
12“Àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí jẹ́ ọba mẹ́wàá. Ṣugbọn wọn kò ì tíì joyè. Wọn óo gba àṣẹ fún wakati kan, àwọn ati ẹranko náà ni yóo jọ lo àṣẹ náà.#Dan 7:24 13Ète kanṣoṣo ni wọ́n ní. Wọn yóo fi agbára wọn ati àṣẹ wọn fún ẹranko náà. 14Wọn yóo bá Ọ̀dọ́ Aguntan náà jagun, ṣugbọn Ọ̀dọ́ Aguntan náà yóo ṣẹgun wọn nítorí pé òun ni Oluwa àwọn oluwa ati Ọba àwọn ọba. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu Ọ̀dọ́ Aguntan náà ninu ìjà ati ìṣẹ́gun náà ni àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí a pè, tí a sì yàn.”
15Ó tún wí fún mi pé, “Àwọn omi tí o rí níbi tí aṣẹ́wó náà ti jókòó ni àwọn eniyan ati gbogbo orílẹ̀-èdè. 16Nígbà tí ó bá yá, àwọn ìwo mẹ́wàá tí o rí yìí ati ẹranko náà, yóo kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn óo tú u sí ìhòòhò, wọn óo bá fi í sílẹ̀ ní ahoro. Wọn óo jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn óo bá dá iná sun ún títí yóo fi jóná ráúráú. 17Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ.
18“Obinrin tí o rí ni ìlú ńlá náà tí ó ń pàṣẹ lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ÌFIHÀN 17: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010