ROMU 10

10
1Ẹ̀yin ará mi, ìfẹ́ ọkàn mi, ati ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọrun fún àwọn Juu, àwọn eniyan mi ni pé kí á gbà wọ́n là. 2Nítorí mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara láti sin Ọlọrun, ṣugbọn wọn kò ní òye bí ó ti yẹ kí wọ́n sìn ín. 3Wọn kò tíì ní òye ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dáni láre, nítorí náà wọ́n wá ọ̀nà ti ara wọn, wọn kò sì fi ara wọn sábẹ́ ètò tí Ọlọrun ṣe fún ìdániláre. 4Nítorí Kristi ti fi òpin sí Òfin láti mú gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ rí ìdáláre níwájú Ọlọrun.
Ìgbàlà fún Gbogbo Eniyan
5Mose kọ sílẹ̀ báyìí nípa ìdáláre tí Òfin lè fúnni pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa wọ́n mọ́, yóo ti ipa wọn rí ìyè.”#Lef 18:5 6Ṣugbọn báyìí ni Ìwé Mímọ́ wí nípa ìdáláre tí à ń gbà nípa igbagbọ, pé, “Má ṣe wí ní ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóo gòkè lọ sọ́run?’ ” (Èyí ni láti mú Kristi sọ̀kalẹ̀.)#Diut 30:12-14 7“Tabi, ‘Ta ni yóo wọ inú ọ̀gbun ilẹ̀ lọ?’ ” (Èyí ni, láti mú Kristi jáde kúrò láàrin àwọn òkú.) 8Ṣugbọn ohun tí ó sọ ni pé, “Ọ̀rọ̀ náà wà nítòsí rẹ, àní, ó wà lẹ́nu rẹ ati lọ́kàn rẹ.” Èyí ni ọ̀rọ̀ igbagbọ tí à ń waasu, pé: 9bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là. 10Nítorí pẹlu ọkàn ni a fi ń gbàgbọ́ láti rí ìdáláre gbà. Ṣugbọn ẹnu ni a fi ń jẹ́wọ́ láti rí ìgbàlà.#Ais 28:16 11Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ tí ojú yóo tì.” 12Nítorí kò sí ìyàtọ̀ kan láàrin Juu ati Giriki. Nítorí Ọlọrun kan náà ni Oluwa gbogbo wọn, ọlá rẹ̀ sì pọ̀ tó fún gbogbo àwọn tí ó bá ń ké pè é. 13Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.”#Joẹl 2:32
14Ṣugbọn báwo ni wọn yóo ṣe ké pe ẹni tí wọn kò gbàgbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gba ẹni tí wọn kò gbúròó rẹ̀ gbọ́? Báwo ni wọn yóo ṣe gbúròó rẹ̀ láìsí àwọn tí ó ń kéde rẹ̀? 15Báwo ni àwọn kan yóo ṣe lọ kéde rẹ̀ láìjẹ́ pé a bá rán wọn lọ? Ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Àwọn tí ó mú ìyìn rere wá mà mọ̀ ọ́n rìn o!”#Ais 52:7 16Ṣugbọn kì í ṣe gbogbo wọn ni ó gba ìyìn rere yìí gbọ́. Aisaya ṣá sọ ọ́ pé, “Oluwa, ta ni ó gba ohun tí a sọ gbọ́?”#Ais 53:1 17Ṣebí ohun tí a bá gbọ́ ni à ń gbàgbọ́, ohun tí a sì gbọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ Kristi?
18Mo wá ń bèèrè, “Ṣé wọn kò ì tíì gbọ́ ni?” Wọ́n kúkú ti gbọ́, nítorí a rí i kà ninu Ìwé Mímọ́ pé,
“Ìró wọn ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè,
àní, ọ̀rọ̀ wọn ti dé òpin ayé.”#O. Daf 19:4
19Mo tún bèèrè: Àbí Israẹli kò mọ̀ ni? Ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ohun tí Mose kọ́kọ́ sọ; ó ní,
“N óo jẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mu yín jowú,
N óo sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tí kò lóye mú kí ara ta yín.”#Diut 32:21
20Aisaya pàápàá kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ kọ́ òun lẹ́nu, ó ní,
“Àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi,
àwọn tí kò bèèrè mi ni mo fi ara hàn fún.”#Ais 65:1
21Ṣugbọn ohun tí ó ní Ọlọrun wí fún Israẹli ni pé, “Láti òwúrọ̀ títí di alẹ́ ni mo na ọwọ́ mi sí àwọn aláìgbọràn ati alágídí eniyan.”#Ais 65:2

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ROMU 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀