I. Kor 8

8
Oúnjẹ Tí A Fi Rúbọ fún Oriṣa
1ṢUGBỌN niti awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe gbogbo wa li o ni ìmọ. Ìmọ a mã fẹ̀, ṣugbọn ifẹ ni gbe-ni-ro.
2Bi ẹnikan ba si rò pe on mọ̀ ohun kan, kò ti imọ̀ bi o ti yẹ ti iba mọ̀.
3Ṣugbọn bi ẹnikẹni ba fẹ Ọlọrun, oluwarẹ̀ li o di mimọ̀ fun u.
4Nitorina niti jijẹ awọn nkan ti a fi rubọ si oriṣa, a mọ̀ pe ohun asan li oriṣa li aiye, ati pe kò si Ọlọrun miran bikoṣe ọkanṣoṣo.
5Nitoripe bi awọn ti a npè li ọlọrun tilẹ wà, iba ṣe li ọrun tabi li aiye (gẹgẹ bi ọ̀pọ ọlọrun ti wà ati ọ̀pọ oluwa,)
6Ṣugbọn fun awa Ọlọrun kan ni mbẹ, Baba, lọwọ ẹniti ohun gbogbo ti wá, ati ti ẹniti gbogbo wa iṣe; ati Oluwa kanṣoṣo Jesu Kristi, nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ati awa nipasẹ rẹ̀.
7Ṣugbọn ìmọ yi kò si ninu gbogbo enia: ṣugbọn awọn ẹlomiran ti o ti mbọriṣa pẹ titi fi di isisiyi jẹ ẹ bi ohun ti a fi rubọ si oriṣa; ati ẹri-ọkàn wọn ti o ṣe ailera si di alaimọ́.
8Ṣugbọn onjẹ ki yio mu wa sunmọ Ọlọrun: nitoripe kì iṣe bi awa ba jẹ li awa san ju; tabi bi awa kò si jẹ li awa buru ju.
9Ṣugbọn ẹ mã kiyesara ki omnira nyin yi ki o máṣe di ohun ikọsẹ fun awọn ti o ṣe ailera.
10Nitoripe bi ẹnikan ba ri ti iwọ ti o ni ìmọ ba joko tì onjẹ ni ile oriṣa, bi on ba ṣe alailera, ọkan rẹ̀ kì yio ha duro lati mã jẹ nkan wọnni ti a fi rubọ si oriṣa?
11Ati nipa ìmọ rẹ li alailera arakunrin, nitori ẹniti Kristi ṣe kú, yio fi ṣegbé?
12Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba nṣẹ̀ si awọn arakunrin bẹ̃, ti ẹ si npa ọkàn wọn ti iṣe ailera lara, ẹnyin nṣẹ̀ si Kristi.
13Nitorina, bi onjẹ ba mu arakunrin mi kọsẹ̀, emi kì yio si jẹ ẹran mọ́ titi lai, ki emi má bà mu arakunrin mi kọsẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Kor 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀