I. Joh Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ọ̀rọ̀ Iṣaaju
Ìdí meji pataki ni ẹni tí ó kọ Ìwé Kinni Johanu fi kọ ọ́. Ìdí kinni ni láti gba àwọn olùkà rẹ̀ ní ìyànjú láti gbé ìgbé-ayé ìrẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun ati Jesu Kristi Ọmọ rẹ̀. Ìdí keji ni láti kìlọ̀ fún wọn láti má tẹ̀lé ẹ̀kọ́ èké tí yóo ba ìrẹ́pọ̀ yìí jẹ́. Ìdí tí irú ẹ̀kọ́ yìí fi wáyé rárá ni pé àwọn eniyan ìgbà náà gbàgbọ́ pé fífi ara kan ayé yìí ní í ṣe okùnfà ibi. Nítorí ìdí èyí, Jesu tíí ṣe Ọmọ Ọlọrun kò lè tún jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara. Àwọn tí wọn ń kọ́ àwọn eniyan ní irú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ yìí sọ pé kí á dá eniyan nídè kúrò ninu kíkó ayé yìí lékàn ni à ń pè ní ìgbàlà. Wọn kò fi mọ bẹ́ẹ̀, wọ́n tún fi kún un pé ìgbàlà kò ní ohunkohun ṣe pẹlu ọ̀ràn ìwà dáradára tabi ìfẹ́ ọmọnikeji ẹni.
Ẹni tí ó kọ ìwé yìí tako irú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ yìí, ó ní eniyan ẹlẹ́ran-ara gan-an ni Jesu, ó wá tẹnumọ́ ọn pé, gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba Jesu gbọ́, tí wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun ní láti fẹ́ràn ọmọnikeji wọn.
Àwọn Ohun tí ó wà ninu Ìwé yìí ní Ìsọ̀rí-ìsọ̀rí
Ọ̀rọ̀ iṣaaju 1:1-4
Ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn 1:5—2:29
Àwọn ọmọ Ọlọrun ati àwọn ọmọ Èṣù 3:1-24
Òtítọ́ ati èké 4:1-6
Iṣẹ́ ìfẹ́ 4:7-21
Igbagbọ tí ń ṣẹgun 5:1-21
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Joh Ọ̀rọ̀ Iṣaaju: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.