I. Sam 24

24
Dafidi dá ẹ̀mí Saulu sí
1O si ṣe nigbati Saulu pada kuro lẹhin awọn Filistini, a si sọ fun u pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni aginju Engedi.
2Saulu si mu ẹgbẹdogun akọni ọkunrin ti a yàn ninu gbogbo Israeli, o si lọ lati wá Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ lori okuta awọn ewurẹ igbẹ.
3O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na.
4Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu.
5O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu.
6On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni.
7Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.
8Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u.
9Dafidi si wi fun Saulu pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi ngbọ́ ọ̀rọ awọn enia pe, Wõ, Dafidi nwá ẹmi rẹ?
10Wõ, oju rẹ ri loni, bi Oluwa ti fi iwọ le mi li ọwọ́ loni ni iho nì: awọn kan ni ki emi ki o pa ọ: ṣugbọn emi dá ọ si; emi si wipe, emi ki yio nawọ́ mi si oluwa mi, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa li on iṣe.
11Pẹlupẹlu, baba mi, wõ, ani wo eti aṣọ rẹ li ọwọ́ mi; nitori emi ke eti aṣọ rẹ, emi ko si pa ọ, si wò, ki o si mọ̀ pe, kò si ibi tabi ẹ̀ṣẹ li ọwọ́ mi, emi kò si ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ ndọdẹ ẹmi mi lati gba a.
12Ki Oluwa ki o ṣe idajọ larin emi ati iwọ, ati ki Oluwa ki o gbẹsan mi lara rẹ; ṣugbọn ọwọ́ mi ki yio si lara rẹ.
13Gẹgẹ bi owe igba atijọ ti wi, Ìwabuburu a ma ti ọdọ awọn enia buburu jade wá; ṣugbọn ọwọ́ mi kì yio si lara rẹ.
14Nitori tani ọba Israeli fi jade? tani iwọ nlepa? okú aja, tabi eṣinṣin?
15Ki Oluwa ki o ṣe onidajọ, ki o si dajọ larin emi ati iwọ, ki o si wò ki o gbejà mi, ki o si gbà mi kuro li ọwọ́ rẹ.
16O si ṣe, nigbati Dafidi si dakẹ ọ̀rọ wọnyi isọ fun Saulu, Saulu si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Saulu si gbe ohùn rẹ̀ soke, o sọkun.
17O si wi fun Dafidi pe, Iwọ ṣe olododo jù mi lọ: nitoripe iwọ ti fi ire san fun mi, emi fi ibi san fun ọ.
18Iwọ si fi ore ti iwọ ti ṣe fun mi hàn loni: nigbati o jẹ pe, Oluwa ti fi emi le ọ li ọwọ́, iwọ kò si pa mi.
19Nitoripe bi enia ba ri ọta rẹ̀, o le jẹ ki o lọ li alafia bi? Oluwa yio si fi ire san eyi ti iwọ ṣe fun mi loni.
20Wõ, emi mọ̀ nisisiyi pe, nitotọ iwọ o jẹ ọba, ilẹ-ọba Israeli yio si fi idi mulẹ si ọ lọwọ.
21Si bura fun mi nisisiyi li orukọ Oluwa, pe, iwọ kì yio ke iru mi kuro lẹhin mi, ati pe, iwọ ki yio pa orukọ mi run kuro ni idile baba mi.
22Dafidi si bura fun Saulu. Saulu si lọ si ile rẹ̀; ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ si iho na.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

I. Sam 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀