I. Sam 28
28
1O si ṣe, ni ijọ wọnni, awọn Filistini si ko awọn ogun wọn jọ, lati ba Israeli jà. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Mọ̀ dajudaju pe, iwọ o ba mi jade lọ si ibi ija, iwọ ati awọn ọmọkunrin rẹ.
2Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Nitotọ iwọ o si mọ̀ ohun ti iranṣẹ rẹ le ṣe. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Nitorina li emi o ṣe fi iwọ ṣe oluṣọ ori mi ni gbogbo ọjọ.
Saulu lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ Abokùúsọ̀rọ̀
3Samueli sì ti kú, gbogbo Israeli si sọkun rẹ̀, nwọn si sin i ni Rama ni ilu rẹ̀. Saulu si ti mu awọn abokusọ̀rọ-ọkunrin, ati awọn abokusọ̀rọ-obinrin kuro ni ilẹ na.
4Awọn Filistini si ko ara wọn jọ, nwọn wá, nwọn si do si Ṣunemu: Saulu si ko gbogbo Israeli jọ, nwọn si tẹdo ni Gilboa.
5Nigbati Saulu si ri ogun awọn Filistini na, on si bẹ̀ru, aiya rẹ̀ si warìri gidigidi.
6Nigbati Saulu si bere lọdọ Oluwa, Oluwa kò da a lohùn nipa alá, nipa Urimu tabi nipa awọn woli.
7Saulu si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ ba mi wá obinrin kan ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ, emi o si tọ ọ lọ, emi o si bere lọdọ rẹ̀. Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Wõ, obinrin kan ni Endori ti o ni ẹmi abokusọ̀rọ.
8Saulu si pa ara dà, o si mu aṣọ miran wọ̀, o si lọ, awọn ọmọkunrin meji si pẹlu rẹ̀, nwọn si wá si ọdọ obinrin na li oru: on si wipe, emi bẹ̀ ọ, fi ẹmi abokusọ̀rọ da nkan fun mi, ki o si mu ẹniti emi o darukọ rẹ̀ fun ọ wá oke fun mi.
9Obinrin na si da a lohùn pe, Wõ, iwọ sa mọ̀ ohun ti Saulu ṣe, bi on ti ke awọn abokusọ̀rọ obinrin, ati awọn abokusọ̀rọ ọkunrin kuro ni ilẹ na; njẹ eha ṣe ti iwọ dẹkùn fun ẹmi mi, lati mu ki nwọn pa mi?
10Saulu si bura fun u nipa Oluwa, pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ìya kan ki yio jẹ ọ nitori nkan yi.
11Obinrin na si bi i pe, Tali emi o mu wá soke fun ọ? on si wipe, Mu Samueli goke fun mi wá.
12Nigbati obinrin na si ri Samueli, o kigbe lohùn rara: obinrin na si ba Saulu sọrọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi tan mi jẹ? nitoripe Saulu ni iwọ iṣe.
13Ọba si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru; kini iwọ ri? obinrin na si wi fun Saulu pe, Emi ri ọlọrun kan nṣẹ́ ti ilẹ wá.
14O si bi i pe, Ẽ ti ri? o si wipe, Ọkunrin arugbo kan li o nṣẹ́ bọ̀; o si fi agbada bora. Saulu si mọ̀ pe, Samueli ni; o si tẹriba, o si wolẹ.
15Samueli si wi fun Saulu pe, Eṣe ti iwọ fi yọ mi lẹnu lati mu mi wá oke? Saulu si dahun o si wipe, Ipọnju nla ba mi; nitoriti awọn Filistini mba mi jagun, Ọlọrun si kọ̀ mi silẹ, kò si da mi lohùn mọ, nipa ọwọ́ awọn woli, tabi nipa alá; nitorina li emi si ṣe pè ọ, ki iwọ ki ole fi ohun ti emi o ṣe hàn mi.
16Samueli si wipe, O ti ṣe bi mi lere nigbati o jẹ pe, Oluwa ti kọ̀ ọ silẹ, o si wa di ọta rẹ?
17Oluwa si ṣe fun ara rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Oluwa si yà ijọba na kuro li ọwọ́ rẹ, o si fi fun aladugbo rẹ, ani Dafidi.
18Nitoripe iwọ kò gbọ́ ohùn Oluwa, iwọ kò si ṣe iṣẹ ibinu rẹ̀ si Amaleki, nitorina li Oluwa si ṣe nkan yi si ọ loni yi:
19Oluwa yio si fi Israeli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi: Oluwa yio si fi ogun Israeli le awọn Filistini lọwọ́.
20Lojukanna ni Saulu ṣubu lulẹ gbọrọ bi o ti gùn, ẹ̀ru si bà a gidigidi, nitori ọ̀rọ Samueli; agbara kò si si fun u: nitoripe kò jẹun li ọjọ na t'ọsan t'oru.
21Obinrin na si tọ Saulu wá, o si ri i pe o wà ninu ibanujẹ pupọ, o si wi fun u pe, Wõ, iranṣẹbinrin rẹ ti gbọ́ ohùn rẹ, emi si ti fi ẹmi mi si ọwọ́ mi, emi si ti gbọ́ ọ̀rọ ti iwọ sọ fun mi.
22Njẹ, nisisiyi, emi bẹ ọ, gbọ́ ohùn iranṣẹbinrin rẹ, emi o si fi onjẹ diẹ siwaju rẹ; si jẹun, iwọ o si li agbara, nigbati iwọ ba nlọ li ọ̀na.
23Ṣugbọn on kọ̀, o si wipe, Emi kì yio jẹun. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ̀, pẹlu obinrin na si rọ̀ ọ; on si gbọ́ ohùn wọn. O si dide kuro ni ilẹ, o si joko lori akete.
24Obinrin na si ni ẹgbọrọ malu kan ti o sanra ni ile; o si yara, o pa a o si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara aiwu.
25On si mu u wá siwaju Saulu, ati siwaju awọn iranṣẹ rẹ̀; nwọn si jẹun. Nwọn si dide, nwọn lọ li oru na.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam 28: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.