I. Sam 9
9
Saulu pàdé Samuẹli
1NJẸ ọkunrin kan ara Benjamini si wà, a ma pe orukọ rẹ̀ ni Kiṣi, ọmọ Abeli, ọmọ Sesori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afia, ara Benjamini ọkunrin alagbara.
2On si ni ọmọkunrin kan, ẹniti a npè ni Saulu, ọdọmọkunrin ti o yàn ti o si ṣe arẹwa, kò si si ẹniti o dara ju u lọ ninu gbogbo awọn ọmọ Israeli: lati ejika rẹ̀ lọ si oke, o ga jù gbogbo awọn enia na lọ.
3Kẹtẹkẹtẹ Kiṣi baba Saulu si nù. Kiṣi si wi fun Saulu ọmọ rẹ̀ pe, Jọwọ mu ọkan ninu awọn iranṣẹkunrin pẹlu rẹ ki o si dide lọ wá kẹtẹkẹtẹ wọnni.
4On kọja niha oke Efraimu, o si kọja niha ilẹ Saliṣa, ṣugbọn nwọn kò ri wọn: nwọn si kọja ni ilẹ Salimu, nwọn kò si si nibẹ; o si kọja ni ilẹ Benjamini, nwọn kò si ri wọn.
5Nigbati nwọn de ilẹ Sufu, Saulu wi fun iranṣẹ-kọnrin rẹ̀ ẹniti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a yipada; ki baba mi ki o má ba fi ãjò awọn kẹtẹkẹtẹ silẹ, ki o si ma kọ ominu nitori wa.
6O si wi fun u pe, Kiye si i, ẹni Ọlọrun kan wà ni ilu yi, o si ṣe ọkunrin ọlọla; gbogbo eyi ti o ba wi, a si ṣẹ: wá, ki a lọ si ibẹ̀; bọya yio fi ọ̀na ti a o gbà hàn wa.
7Saulu si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Bi awa ba lọ, kili awa o mu lọ fun ọkunrin na? nitoripe akara tan ni apò wa, ko si si ọrẹ ti a o mu tọ̀ ẹni Ọlọrun na: kili awa ni?
8Iranṣẹ na si da Saulu lohùn wipe, Mo ni idamẹrin ṣekeli fadaka lọwọ́, eyi li emi o fun ẹni Ọlọrun na, ki o le fi ọ̀na wa hàn wa.
9(Ni Israeli latijọ, nigbati ọkunrin kan ba lọ bere lọdọ Ọlọrun, bayi ni ima wi, Wá, ẹ jẹ ki a lọ sọdọ arina na, nitori ẹni ti a npe ni woli nisisiyi, on ni a npe ni arina nigba atijọ ri)
10Nigbana ni Saulu wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Iwọ wi rere; wá, jẹ ki a lọ. Bẹ̃ni nwọn si lọ si ilu na nibiti ẹni Ọlọrun nã gbe wà.
11Bi nwọn ti nlọ si oke ilu na, nwọn ri awọn wundia ti nlọ fa omi, nwọn bi wọn lere wipe, Arina mbẹ nihin bi?
12Nwọn si da wọn lohùn, nwọn si wipe, O mbẹ; wo o, o mbẹ niwaju nyin: yara nisisiyi nitoripe loni li o de ilu; nitoriti ẹbọ mbẹ fun awọn enia loni ni ibi giga.
13Bi ẹnyin ti nlọ si ilu na, ẹnyin o si ri i, ki o to lọ si ibi giga lati jẹun: nitoripe awọn enia kì yio jẹun titi on o fi de, nitori on ni yio sure si ẹbọ na; lẹhin eyini li awọn ti a pè yio to jẹun. Ẹ goke lọ nisisiyi; lakoko yi ẹnyin o ri i.
14Nwọn goke lọ si ilu na: bi nwọn si ti nwọ ilu na, kiye si i, Samueli mbọ̀ wá pade wọn, lati goke lọ si ibi giga na,
15Oluwa ti wi leti Samueli ni ijọ kan ki Saulu ki o to de, wipe,
16Niwoyi ọla emi o ran ọkunrin kan lati ilẹ Benjamini wá si ọ, iwọ o si da ororo si i lori ki o le jẹ olori-ogun Israeli awọn enia mi, yio si gbà awọn enia mi là lọwọ awọn Filistini: nitori emi ti bojuwo awọn enia mi, nitoripe ẹkun wọn ti de ọdọ mi.
17Nigbati Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun u pe, Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rẹ̀ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi.
18Saulu si sunmọ Samueli li ẹnu-ọna ilu, o si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ ọ, nibo ni ile arina gbe wà?
19Samueli da Saulu lohùn o si wipe, emi ni arina na: goke lọ siwaju mi ni ibi giga, ẹ o si ba mi jẹun loni, li owurọ̀ emi o si jẹ ki o lọ, gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ li emi o sọ fun ọ.
20Niti awọn kẹtẹkẹtẹ rẹ ti o ti nù lati iwọn ijọ mẹta wá, má fi ọkàn si wọn; nitoriti nwọn ti ri wọn. Si tani gbogbo ifẹ, Israeli wà? Ki iṣe si ọ ati si ile baba rẹ?
21Saulu si dahùn o si wipe, Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israeli? idile mi kò si rẹhìn ninu gbogbo ẹya Benjamini? ẽsi ti ṣe ti iwọ sọrọ yi si mi?
22Samueli si mu Saulu ati iranṣẹ rẹ̀, o si mu wọn wọ inu gbàngàn, o si fun wọn ni ijoko lãrin awọn agbagba ninu awọn ti a pè, nwọn si to ọgbọ̀n enia.
23Samueli si wi fun alase pe, Mu ipin ti mo ti fi fun ọ wá, eyi ti mo ti sọ fun ọ pe, Ki o fi i pamọ sọdọ rẹ.
24Alase na si gbe ejika na, ati eyi ti o wà lori rẹ̀, o si gbe e kalẹ niwaju Saulu. Samueli si wipe, Wo eyi ti a fi silẹ! fà a sọdọ rẹ, ki o si ma jẹ: nitoripe titi di isisiyi li ati pa a mọ fun ọ lati igbati mo ti wipe, emi ti pe awọn enia na. Bẹ̃ni Saulu si ba Samueli jẹun li ọjọ na.
25Nigbati nwọn sọkalẹ lati ibi giga nì wá si ilu, Samueli si ba Saulu sọrọ lori orule.
Samuẹli ta òróró sí Saulu lórí láti yàn án ní ọba
26Nwọn si dide ni kutukutu: o si ṣe, li afẹmọjumọ, Samueli si pe Saulu sori orule, wipe, Dide, emi o si ran ọ lọ. Saulu si dide, awọn mejeji sì jade, on ati Samueli, si gbangba.
27Bi nwọn si ti nsọkalẹ lọ si ipẹkun ilu na, Samueli wi fun Saulu pe, Wi fun iranṣẹ ki o kọja si iwaju wa, (o si kọja) ṣugbọn ki iwọ ki o duro diẹ, ki emi ki o le fi ọ̀rọ Ọlọrun hàn ọ́.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Sam 9: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.