I. Tim 3
3
Irú Ẹni Tí Olùdarí Ìjọ Ní láti Jẹ́
1OTITỌ ni ọ̀rọ na, bi ẹnikan ba fẹ oyè biṣopu, iṣẹ rere li o nfẹ.
2Njẹ biṣopu jẹ alailẹgan, ọkọ aya kan, oluṣọra, alairekọja, oniwa yiyẹ, olufẹ alejò ṣiṣe, ẹniti o le ṣe olukọ.
3Ki o má jẹ ọmuti, tabi onijà, tabi olojukokoro, bikoṣe onisũru, ki o má jẹ onija, tabi olufẹ owo;
4Ẹniti o kawọ ile ara rẹ̀ girigiri, ti o mu awọn ọmọ rẹ̀ tẹriba pẹlu ìwa àgba gbogbo;
5(Ṣugbọn bi enia kò ba mọ̀ bi ã ti ṣe ikawọ ile ara rẹ̀, on o ha ti ṣe le tọju ijọ Ọlọrun?)
6Ki o má jẹ ẹni titun, kí o má bã gbéraga, ki o si ṣubu sinu ẹbi Èṣu.
7O si yẹ kí o ni ẹri rere pẹlu lọdọ awọn ti mbẹ lode: kí o má ba bọ sinu ẹ̀gan ati sinu idẹkun Èṣu.
Irú Ẹni Tí Diakoni Ní láti Jẹ́
8Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn diakoni lati ni ìwa àgba, ki nwọn má jẹ ẹlẹnu meji, kì nwọn má fi ara wọn fun waini pupọ̀, ki nwọn má jẹ olojukokoro.
9Ki nwọn mã di ohun ijinlẹ igbagbọ́ mu li ọkàn funfun.
10Ki a si kọ́ wá idi awọn wọnyi daju pẹlu; nigbana ni ki a jẹ ki nwọn jẹ oyè diakoni, bi nwọn ba jẹ alailẹgan.
11Bẹ̃ gẹgẹ li o yẹ fun awọn obinrin lati ni iwa àgba, kì nwọn má jẹ asọrọ-ẹni-lẹhin bikoṣe alairekọja, olõtọ li ohun gbogbo.
12Ki awọn diakoni jẹ ọkọ obinrin kan, ki nwọn ki o káwọ awọn ọmọ wọn ati ile ara wọn daradara.
13Nitori awọn ti o lò oyè diakoni daradara rà ipo rere fun ara wọn, ati igboiya pupọ ni igbagbọ́ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.
Ohun Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀sìn Wa
14Iwe nkan wọnyi ni mo kọ si ọ, mo si nreti ati tọ̀ ọ wá ni lọ̃lọ̃.
15Ṣugbọn bi mo ba pẹ, ki iwọ ki o le mọ̀ bi o ti yẹ fun awọn enia lati mã huwa ninu ile Ọlọrun, ti iṣe ijọ Ọlọrun alãye, ọwọ̀n ati ipilẹ otitọ.
16Laiṣiyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ ìwa-bi-Ọlọrun, ẹniti a fihan ninu ara, ti a dalare ninu Ẹmí, ti awọn angẹli ri, ti a wasu rẹ̀ lãrin awọn orilẹ-ede, ti a gbagbọ ninu aiye, ti a gba soke sinu ogo.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
I. Tim 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.