II. Kro 22
22
Ahasaya Ọba Juda
(II. A. Ọba 8:25-29; 9:21-28)
1AWỌN olugbe Jerusalemu, si fi Ahasiah, ọmọ rẹ̀ abikẹhin, jọba ni ipò rẹ̀: nitori awọn ẹgbẹ́ ogun, ti o ba awọn ara Arabia wá ibudo, ti pa gbogbo awọn ẹgbọn. Bẹ̃ni Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, jọba.
2Ẹni ọdun mejilelogun ni Ahasiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun kan ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Ataliah, ọmọbinrin Omri.
3On pẹlu rìn li ọ̀na Ahabu: nitori iya rẹ̀ ni igbimọ̀ rẹ̀ lati ṣe buburu.
4O si ṣe buburu loju Oluwa bi ile Ahabu: nitori awọn wọnyi li o nṣe igbimọ̀ rẹ̀ lẹhin ikú baba rẹ̀ si iparun rẹ̀.
5O tẹle imọ̀ran wọn pẹlu; o si ba Jehoramu, ọmọ Ahabu, ọba Israeli, lọ iba Hasaeli, ọba Siria jagun, ni Ramoti-Gileadi: awọn ara Siria si ṣá Jehoramu li ọgbẹ.
6O si pada lọ iwora ni Jesreeli, nitori ọgbẹ ti a ṣá a ni Rama, nigbati o fi ba Hasaeli, ọba Siria jà. Ahasiah, ọmọ Jehoramu, ọba Juda, si sọ̀kalẹ lọ iwò Jehoramu, ọmọ Ahabu, ni Jesreeli, nitoriti o ṣaisan.
7Iparun Ahasiah lati ọwọ Ọlọrun wá ni, nipa wiwá sọdọ Jehoramu: nigbati o si de, o si ba Jehoramu jade tọ̀ Jehu, ọmọ Nimṣi, ẹniti Oluwa fi ororo yàn lati ké ile Ahabu kuro.
8O si ṣe nigbati Jehu nmu idajọ ṣẹ sori ile Ahabu, o si ri awọn ijoye Juda, ati awọn ọmọ awọn arakunrin Ahasiah, ti nṣe iranṣẹ fun Ahasiah, o si pa wọn.
9O si wá Ahasiah: nwọn si mu u, (on sa ti fi ara pamọ́ ni Samaria,) nwọn si mu u tọ̀ Jehu wá: nigbati nwọn si pa a tan, nwọn sìn i: nitori ti nwọn wipe, ọmọ Jehoṣafati ni, ẹniti o wá Oluwa tọkàntọkan rẹ̀. Bẹ̃ni kò si ẹnikan ni ile Ahasiah ti o yẹ fun ijọba.
Atalaya, Ọbabinrin ní Juda
(II. A. Ọba 11:1-3)
10Ṣugbọn nigbati Ataliah, iya Ahasiah, ri pe ọmọ on kú, o dide o si run gbogbo iru ọmọ ijọba ile Judah.
11Ṣugbọn Jehoṣabeati, ọmọbinrin ọba, mu Joaṣi, ọmọ Ahasiah, o ji i kuro ninu awọn ọmọ ọba ti a pa, o fi on ati olutọ rẹ̀ sinu yẹwu Ibusùn. Bẹ̃ni Jehoṣabeati, ọmọbinrin Jehoramu ọba, aya Jehoiada, alufa, (nitori arabinrin Ahasiah li on) o pa a mọ́ kuro lọdọ Ataliah ki o má ba pa a.
12O si wà pẹlu wọn ni pipamọ́ ninu ile Ọlọrun li ọdun mẹfa: Ataliah si jọba lori ilẹ na.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 22: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.