II. Kro 29
29
Hesekaya, Ọba Juda
(II. A. Ọba 18:1-3)
1ẸNI ọdun mẹdọgbọn ni Hesekiah, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba fun ọdun mọkandilọgbọn ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Abijah, ọmọbinrin Sekariah.
2O si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Dafidi, baba rẹ̀, ti ṣe.
Yíya Tẹmpili sí Mímọ́
3Li ọdun kini ijọba rẹ̀ li oṣù kini, o ṣí ilẹkun ile Oluwa, o si tun wọn ṣe.
4O si mu awọn alufa wá ati awọn ọmọ Lefi, o si kó wọn jọ si ita ila-õrun.
5O si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ temi, ẹnyin ọmọ Lefi; ẹ yà ara nyin si mimọ́ nisisiyi, ki ẹ si yà ile Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin si mimọ́, ki ẹ si kó ohun aimọ́ na jade kuro ni ibi mimọ́.
6Awọn baba wa sa ti dẹṣẹ, nwọn si ti ṣe ibi li oju Oluwa Ọlọrun wa, nwọn si ti kọ̀ ọ silẹ, nwọn si ti yi oju wọn pada kuro ni ibugbe Oluwa, nwọn si ti pa ẹhin wọn da.
7Nwọn ti tì ilẹkun iloro na pẹlu, nwọn si ti pa fitila, nwọn kò si sun turari, bẹ̃ni nwọn kò ru ẹbọ sisun ni ibi mimọ́ si Ọlọrun Israeli.
8Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri.
9Sa wò o, awọn baba wa ti ti ipa idà ṣubu, ati awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, ati awọn obinrin wa wà ni igbekun nitori eyi.
10Njẹ o wà li ọkàn mi lati ba Oluwa Ọlọrun Israeli dá majẹmu, ki ibinu rẹ̀ kikan ki o le yipada kuro lọdọ wa.
11Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari.
12Nigbana li awọn ọmọ Lefi dide, Mahati, ọmọ Amasai, ati Joeli, ọmọ Asariah, ninu awọn ọmọ Kohati: ati ninu awọn ọmọ Merari, Kiṣi, ọmọ Abdi, ati Asariah, ọmọ Jehaleeli: ati ninu awọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma, ati Edeni, ọmọ Joah:
13Ati ninu awọn ọmọ Elisafani, Ṣimri ati Jegieli: ati ninu awọn ọmọ Asafu, Sekariah ati Mattaniah.
14Ati ninu awọn ọmọ Hemani, Jehieli ati Ṣimei: ati ninu awọn ọmọ Jedutuni, Ṣemaiah ati Ussieli.
15Nwọn si kó awọn arakunrin wọn jọ, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si wá nipa aṣẹ ọba gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, lati gbá ile Oluwa mọ́.
16Awọn alufa si wọ inu ile Oluwa lọhun lọ, lati gbá a mọ́, nwọn si mu gbogbo ẽri ti nwọn ri ninu tempili Oluwa jade si inu agbala ile Oluwa. Awọn ọmọ Lefi si kó o, nwọn si rù u jade gbangba lọ si odò Kidroni.
17Njẹ nwọn bẹ̀rẹ li ọjọ kini oṣù kini, lati yà a si mimọ́, ati li ọjọ kẹjọ oṣù na, nwọn de iloro Oluwa: bẹ̃ni nwọn fi ọjọ mẹjọ yà ile Oluwa si mimọ́; ati li ọjọ kẹrindilogun oṣù kini na, nwọn pari rẹ̀.
A Tún Tẹmpili Yà sí Mímọ́
18Nigbana ni nwọn wọle tọ̀ Hesekiah ọba, nwọn si wipe: Awa ti gbá ile Oluwa mọ́, ati pẹpẹ ẹbọ sisun, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀, ati tabili akara-ifihan, pẹlu gbogbo ohun-elo rẹ̀.
19Pẹlupẹlu gbogbo ohun-elo, ti Ahasi, ọba, ti sọ di alaimọ́ ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, li akokò ijọba rẹ̀, li awa ti pese ti awa si ti yà si mimọ́, si kiyesi i, nwọn mbẹ niwaju pẹpẹ Oluwa.
20Nigbana ni Hesekiah, ọba, dide ni kutukutu; o si kó awọn olori ilu jọ, o si gòke lọ sinu ile Oluwa.
21Nwọn si mu akọ-malu meje wá, ati àgbo meje, ati ọdọ-agutan meje, ati obukọ meje fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ijọba na, ati fun ibi mimọ́ na, ati fun Juda. O si paṣẹ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, lati fi wọn rubọ lori pẹpẹ Oluwa.
22Bẹ̃ni awọn alufa pa awọn akọ-malu na, nwọn si gba ẹ̀jẹ na, nwọn si fi wọ́n ara pẹpẹ: bẹ̃ gẹgẹ nigbati nwọn pa awọn àgbo, nwọn fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ; nwọn pa awọn ọdọ-agutan pẹlu nwọn si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ara pẹpẹ.
23Nwọn si mu awọn òbukọ ẹbọ-ẹ̀ṣẹ wá siwaju ọba ati ijọ enia na: nwọn si fi ọwọ wọn le wọn lori.
24Awọn alufa si pa wọn, nwọn si fi ẹ̀jẹ wọn ṣe ilaja lori pẹpẹ, lati ṣe etutu fun gbogbo Israeli; nitoriti ọba paṣẹ, ki a ṣe ẹbọ sisun ati ẹbọ-ẹ̀ṣẹ fun gbogbo Israeli.
25O si mu awọn ọmọ Lefi duro ninu ile Oluwa, pẹlu kimbali, pẹlu ohun-elo orin, ati pẹlu duru, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi, ati ti Gadi, ariran ọba, ati Natani, woli, nitori aṣẹ Oluwa ni lati ọwọ awọn woli rẹ̀.
26Awọn ọmọ Lefi si duro pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ati awọn alufa pẹlu ipè.
27Hesekiah si paṣẹ lati ru ẹbọ sisun lori pẹpẹ na. Nigbati ẹbọ sisun na si bẹ̀rẹ, orin Oluwa bẹ̀rẹ pẹlu ipè ati pẹlu ohun-elo orin Dafidi, ọba Israeli.
28Gbogbo ijọ enia na si wolẹ sìn, awọn akọrin, kọrin, ati awọn afunpè fun: gbogbo wọnyi si wà bẹ̃ titi ẹbọ sisun na fi pari tan.
29Nigbati nwọn si ṣe ipari ẹbọ riru, ọba ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ tẹ̀ ara wọn ba, nwọn si sìn.
30Pẹlupẹlu Hesekiah ọba, ati awọn ijoye paṣẹ fun awọn ọmọ Lefi, lati fi ọ̀rọ Dafidi ati ti Asafu ariran, kọrin iyìn si Oluwa: nwọn si fi inu-didùn kọrin iyìn, nwọn si tẹri wọn ba, nwọn si sìn.
31Nigbana ni Hesekiah dahùn, o si wipe, Nisisiyi, ọwọ nyin kún fun ẹ̀bun fun Oluwa, ẹ ṣunmọ ihin, ki ẹ si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá sinu ile Oluwa. Ijọ ẹnia si mu ẹbọ ati ọrẹ-ọpẹ wá; ati olukuluku ti ọkàn rẹ̀ fẹ, mu ẹbọ sisun wá.
32Iye ẹbọ sisun, ti ijọ enia mu wá, si jẹ ãdọrin akọ-malu, ati ọgọrun àgbo, ati igba ọdọ-agutan: gbogbo wọnyi si ni fun ẹbọ-sisun si Oluwa.
33Awọn ohun ìyasi-mimọ́ si jẹ ẹgbẹta malu, ati ẹgbẹdogun agutan.
34Ṣugbọn awọn alufa kò to, nwọn kò si le họ gbogbo awọn ẹran ẹbọ sisun na: nitorina awọn arakunrin wọn, awọn ọmọ Lefi ràn wọn lọwọ, titi iṣẹ na fi pari, ati titi awọn alufa iyokù fi yà ara wọn si mimọ́: nitori awọn ọmọ Lefi ṣe olõtọ li ọkàn jù awọn alufa lọ lati yà ara wọn si mimọ́.
35Ati pẹlu, awọn ẹbọ sisun papọju, pẹlu ọra ẹbọ-alafia, pẹlu ẹbọ ohun-mimu fun ẹbọ sisun. Bẹ̃li a si to iṣẹ́-ìsin ile Oluwa li ẹsẹsẹ.
36Hesekiah si yọ̀, ati gbogbo enia pe, Ọlọrun ti mura awọn enia na silẹ: nitori li ojiji li a ṣe nkan na.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kro 29: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.