II. Kor 5
5
1NITORI awa mọ̀ pe, bi ile agọ́ wa ti aiye bá wó, awa ni ile kan lati ọdọ Ọlọrun, ile ti a kò fi ọwọ́ kọ́, ti aiyeraiye ninu awọn ọrun.
2Nitori nitõtọ awa nkerora ninu eyi, awa si nfẹ gidigidi lati fi ile wa lati ọrun wá wọ̀ wa:
3Bi o ba ṣepe a ti wọ̀ wa li aṣọ, a kì yio bá wa ni ìhoho.
4Nitori awa ti mbẹ ninu agọ́ yi nkerora nitõtọ, ẹrù npa wa: kì iṣe nitori ti awa nfẹ ijẹ alaiwọ̀ṣọ, ṣugbọn ki a le wọ̀ wa li aṣọ, ki iyè ki o le gbé ara kiku mì.
5Njẹ ẹniti o ṣe wa fun nkan yi ni Ọlọrun, ẹniti o si ti fi akọso Ẹmí fun wa pẹlu.
6Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa:
7(Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:)
8Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa.
9Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀.
10Nitoripe gbogbo wa kò le ṣaima fi ara hàn niwaju itẹ́ idajọ Kristi; ki olukuluku ki o le gbà nkan wọnni ti o ṣe ninu ara, gẹgẹ bi eyi ti o ti ṣe, ibã ṣe rere ibã ṣe buburu.
Iṣẹ́ Ìlàjà
11Nitorina bi awa ti mọ̀ ẹ̀ru Oluwa, awa nyi enia li ọkàn pada; ṣugbọn a nfi wa hàn fun Ọlọrun; mo si gbagbọ́ pe, a si fi wa hàn li ọkàn nyin pẹlu.
12Nitori awa kò si ni tún mã yìn ara wa si nyin mọ́, ṣugbọn awa fi àye fun nyin lati mã ṣogo nitori wa, ki ẹ le ni ohun ti ẹ ó fi da wọn lohùn, awọn ti nṣogo lode ara kì isi iṣe li ọkàn.
13Nitorina bi ori wa ba bajẹ, fun Ọlọrun ni: tabi bi iye wa ba walẹ̀, fun nyin ni.
14Nitori ifẹ Kristi nrọ̀ wa; nitori awa rò bayi, pe bi ẹnikan ba ti kú fun gbogbo enia, njẹ gbogbo wọn li o ti kú:
15O si ti kú fun gbogbo wọn, pe ki awọn ti o wà lãye ki o má si ṣe wà lãye fun ara wọn mọ́, bikoṣe fun ẹniti o kú nitori wọn, ti o si ti jinde.
16Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́.
17Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun.
18Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa;
19Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.
20Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja.
21Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Kor 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.