II. Joh 1
1
Ìkíni
1EMI alàgba si ayanfẹ obinrin ọlọlá ati awọn ọmọ rẹ̀, awọn ti mo fẹ li otitọ; kì si iṣe emi nikan, ṣugbọn gbogbo awọn ti o mọ̀ otitọ pẹlu;
2Nitori otitọ ti ngbé inu wa, yio si mã ba wa gbé titi.
3Õre-ọfẹ, ãnu, ati alafia, yio wà pẹlu wa, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati lati ọdọ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, ninu otitọ ati ninu ifẹ.
Ẹ Máa Gbé Inú Ẹ̀kọ́ Kristi
4Mo yọ̀ gidigidi pe mo ti ri ninu awọn ọmọ rẹ ti nrin ninu otitọ, ani bi awa ti gbà ofin lati ọdọ Baba.
5Njẹ nisisiyi mo bẹ̀ ọ, obinrin ọlọlá, kì iṣe bi ẹnipe emi nkọwe ofin titun kan si ọ, bikọse eyi ti awa ti ni li àtetekọṣe, pe ki awa ki o fẹràn ara wa.
6Eyi si ni ifẹ, pe, ki awa ki o mã rìn nipa ofin rẹ̀. Eyi li ofin na, ani bi ẹ ti gbọ́ li àtetekọṣe, pe, ki ẹnyin ki o mã rìn ninu rẹ̀.
7Nitori ẹlẹtàn pupọ̀ ti jade wá sinu aiye, awọn ti kò jẹwọ pe Jesu Kristi wá ninu ara. Eyi li ẹlẹtàn ati Aṣodisi Kristi.
8Ẹ kiyesara nyin, ki ẹ má sọ iṣẹ ti awa ti ṣe nù, ṣugbọn ki ẹnyin ki o ri ère kíkún gbà.
9Olukuluku ẹniti o ba nru ofin ti kò si duro ninu ẹkọ́ Kristi, kò gba Ọlọrun. Ẹniti o ba duro ninu ẹkọ́, on li o gbà ati Baba ati Ọmọ.
10Bi ẹnikẹni bá tọ̀ nyin wá, ti kò si mu ẹkọ́ yi wá, ẹ máṣe gbà a si ile, ki ẹ má si ṣe kí i.
11Nitori ẹniti o ba ki i, o ni ọwọ́ ninu iṣẹ buburu rẹ̀.
Ìdágbére
12Bi mo ti ni ohun pupọ̀ lati kọwe si nyin, emi kò fẹ lo tákàdá ati tàdãwa. Ṣugbọn emi ni ireti lati tọ nyin wá ati lati ba nyin sọrọ lojukoju, ki ayọ̀ nyin ki o le kún.
13Awọn ọmọ arabinrin rẹ ayanfẹ ki ọ. Amin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. Joh 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.