II. A. Ọba 5
5
Naamani Gba Ìwòsàn
1NJẸ Naamani, olori-ogun ọba Siria, jẹ enia nla niwaju oluwa rẹ̀, ati ọlọla, nitori nipa rẹ̀ ni Oluwa ti fi iṣẹgun fun Siria: on si jẹ alagbara akọni ọkunrin ṣugbọn adẹtẹ̀ ni.
2Awọn ara Siria si ti jade lọ ni ẹgbẹ́-ẹgbẹ́, nwọn si ti mu ọmọbinrin kekere kan ni igbèkun lati ilẹ Israeli wá; on si duro niwaju obinrin Naamani.
3On si wi fun iya rẹ̀ pe, oluwa mi iba wà niwaju woli ti mbẹ ni Samaria! nitõtọ on iba wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.
4On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi.
5Ọba Siria si wipe, Wá na, lọ, emi o si fi iwe ranṣẹ si ọba Israeli. On si jade lọ, o si mu talenti fàdakà mẹwa lọwọ, ati ẹgbãta iwọ̀n wurà, ati ipãrọ aṣọ mẹwa.
6On si mu iwe na tọ̀ ọba Israeli wá, wipe, Njẹ nisisiyi nigbati iwe yi ba de ọdọ rẹ, kiyesi i, emi rán Naamani iranṣẹ mi si ọ, ki iwọ ki o le wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀.
7O si ṣe, nigbati ọba Israeli kà iwe na tan, o si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si wipe, Emi ha iṣe Ọlọrun, lati pa ati lati sọ di ãyè, ti eleyi fi ranṣẹ si mi lati ṣe awòtan enia kan kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀? nitorina, ẹ rò o wò, mo bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò o bi on ti nwá mi ni ijà.
8O si ṣe, nigbati Eliṣa enia Ọlọrun gbọ́ pe, ọba Israeli fà aṣọ rẹ̀ ya, o si ranṣẹ si ọba wipe, Ẽṣe ti iwọ fi fà aṣọ rẹ ya? jẹ ki o tọ̀ mi wá nisisiyi, on o si mọ̀ pe, woli kan mbẹ ni Israeli.
9Bẹ̃ni Naamani de pẹlu awọn ẹṣin rẹ̀ ati pẹlu kẹkẹ́ rẹ̀, o si duro li ẹnu-ọ̀na ile Eliṣa.
10Eliṣa si ràn iranṣẹ kan si i wipe, Lọ, ki o si wẹ̀ ni Jordani nigba meje, ẹran-ara rẹ yio si tun bọ̀ sipò fun ọ, iwọ o si mọ́.
11Ṣugbọn Naamani binu, o si pada lọ, o si wipe, Kiyesi, i, mo rò ninu mi pe, dajudaju on o jade tọ̀ mi wá, yio si duro, yio si kepè orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, yio si fi ọwọ rẹ̀ pa ibẹ̀ na, yio si ṣe awòtan ẹ̀tẹ na.
12Abana ati Farpari, awọn odò Damasku kò ha dara jù gbogbo awọn omi Israeli lọ? emi kì iwẹ̀ ninu wọn ki emi si mọ́? Bẹ̃li o yipada, o si jade lọ ni irúnu.
13Awọn iranṣẹ rẹ̀ si sunmọ ọ, nwọn si ba a sọ̀rọ, nwọn si wipe, Baba mi, woli iba wi fun ọ pe, ki o ṣe ohun nla kan, iwọ kì ba ti ṣe e bi? melomelo, nigbati o wi fun ọ pe, Wẹ̀, ki o si mọ́?
14Nigbana ni o sọ̀kalẹ, o si tẹ̀ ara rẹ̀ bọ inu Jordani nigba meje, gẹgẹ bi ọ̀rọ enia Ọlọrun: ẹran-ara rẹ̀ si tún pada bọ̀ gẹgẹ bi ẹran-ara ọmọ kekere, on si mọ́.
15O si pada tọ̀ enia Ọlọrun na lọ, on, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀, nwọn si wá, nwọn duro niwaju rẹ̀: on si wipe, wõ, nisisiyi ni mo to mọ̀ pe, Kò si Ọlọrun ni gbogbo aiye, bikòṣe ni Israeli: njẹ nisisiyi, emi bẹ̀ ọ, gbà ẹbun lọwọ iranṣẹ rẹ.
16Ṣugbọn on wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, niwaju ẹniti emi duro, emi kì yio gbà nkan. O si rọ̀ ọ ki o gbà, ṣugbọn on kọ̀.
17Naamani si wipe, Njẹ, emi bẹ̀ ọ, a kì yio ha fi erupẹ ẹrù ibàka meji fun iranṣẹ rẹ? nitori lati oni lọ iranṣẹ rẹ kì yio rubọ sisun, bẹ̃ni kì yio rubọ si awọn ọlọrun miran, bikòṣe si Oluwa.
18Ninu nkan yi ni ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ, nigbati oluwa mi ba lọ si ile Rimmoni lati foribalẹ nibẹ, ti on ba si fi ara tì ọwọ mi, ti emi tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni: nigbati mo ba tẹ̀ ara mi ba ni ile Rimmoni, ki Oluwa ki o darijì iranṣẹ rẹ ninu nkan yi.
19On si wi fun u pe, Mã lọ ni alãfia. Bẹ̃ni o si jade lọ jinà diẹ kuro lọdọ rẹ̀.
20Ṣugbọn Gehasi, iranṣẹ Eliṣa enia Ọlọrun na wipe, Kiyesi i, oluwa mi ti dá Naamani ara Siria yi si, niti kò gbà nkan ti o mu wá lọwọ rẹ̀: ṣugbọn, bi Oluwa ti mbẹ, emi o sare bá a, emi o si gbà nkan lọwọ rẹ̀.
21Bẹ̃ni Gehasi lepa Naamani. Nigbati Naamani ri ti nsare bọ̀ lẹhin on, o sọ̀kalẹ kuro ninu kẹkẹ́ lati pade rẹ̀, o si wipe, Alafia kọ?
22On si wipe, Alafia ni. Oluwa mi rán mi, wipe, Kiyesi i, nisisiyi ni ọdọmọkunrin meji ninu awọn ọmọ woli ti òke Efraimu wá ọdọ mi; emi bẹ̀ o, fun wọn ni talenti fadakà kan, ati ipàrọ aṣọ meji.
23Naamani si wipe, Fi ara balẹ, gbà talenti meji. O si rọ̀ ọ, o si dì talenti fadakà meji sinu apò meji, pẹlu ipàrọ aṣọ meji, o si gbé wọn rù ọmọ-ọdọ rẹ̀ meji; nwọn si rù wọn niwaju rẹ̀.
24Nigbati o si de ibi ile ìṣọ, o gbà wọn lọwọ wọn, o si tò wọn sinu ile: o si jọ̀wọ awọn ọkunrin na lọwọ lọ, nwọn si jade lọ.
25Ṣugbọn on wọ̀ inu ile lọ, o si duro niwaju oluwa rẹ̀. Eliṣa si wi fun u pe, Gehasi, nibo ni iwọ ti mbọ̀? On si wipe, Iranṣẹ rẹ kò lọ ibikibi.
26On si wi fun u pe, Ọkàn mi kò ha ba ọ lọ, nigbati ọkunrin na fi yipada kuro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ lati pade rẹ? Eyi ha iṣe akokò ati gbà fadakà, ati lati gbà aṣọ, ati ọgbà-olifi ati ọgbà-ajara, ati àgutan, ati malu, ati iranṣékunrin ati iranṣẹbinrin?
27Nitorina ẹ̀tẹ Naamani yio lẹ mọ ọ, ati iru-ọmọ rẹ titi lai. On si jade kuro niwaju rẹ̀, li adẹtẹ̀ ti o funfun bi ojodidì.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
II. A. Ọba 5: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.